VGN L'AWỌN ṢETAN LATI GBOGUN TI IWA ỌDARAN LASIKO ATI LẸYIN ỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 2, 2020

VGN L'AWỌN ṢETAN LATI GBOGUN TI IWA ỌDARAN LASIKO ATI LẸYIN ỌDUN


Ileeṣẹ eto aabo Fijilante lorilẹ-ede Naijiria, Vigilante Group of Nigeria ti sọ pe awọn ti bẹrẹ igbaradi lati gbogun ti iwa ọdaran lasiko ati lẹyin ayẹyẹ pọpọṣinṣin ọdun to n bọ lọna.
 
Ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tusidee ana ni igbakeji adari ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba, ACG Oluṣọla Jimọh Ọlawale sọrọ naa lasiko to n b'awọn oniroyin sọrọ nibi idanilẹkọọ ẹgbẹ naa to waye nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
 
Nibẹ ni wọn tun ti rawọ ẹbẹ síjọba orilẹ-ede Naijiria, ipinlẹ Ogun at'awọn ipinlẹ yooku kaakiri Naijiria lati pese awọn nnkan to le mu ki eto aabo rọrun f'awọn.
 
Lara awọn to wa nibi eto idanilẹkọọ ọlọjọ marun-un naa ni: igbakeji ọga agba pata n'ipinlẹ Ogun, Ọyọ, Ọṣun, Eko, Ekiti ati Ondo, to fi mọ agbẹnu ẹgbẹ naa lapapọ, Ọlanrewaju Nureni Adedoyin.


Oluṣọla Ọlawale sọ pe aisi irinṣẹ eto aabo n mu ifasẹyin ba  iṣẹ wọn lọpọ igba, bo tilẹ jẹ pe awọn ko dẹkun lati maa gbogun ti iwa ọdaran loore-koore.
 
B'awọn naa n'igba to n sọrọ nipa idanilẹkọọ yii, o ni lẹyin idanilẹkọọ naa, awọn akopa yoo tun ni imọ tuntun nipa ọna ti wọn yoo gbe eto aabo wọn gba, ki wọn si mọ pataki eto aabo ju eyi ti wọn ti mọ tẹlẹ lọ.
 
Ninu ọrọ tirẹ, adari ẹgbẹ naa n'ipinlẹ Ogun,  Oluṣọla Temitọpẹ Odogu sọ pe asiko ti a wa yii, awọn araale le sun asundọkan nitori pe  gbogbo eto lo ti pari patapata lati tubọ gbogun ti iwa ọdaran kaakiri ipinlẹ naa, to si l'awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ti mura silẹ, paapaa fun ti ayẹyẹ ọdun keresimesi ati ọdun tuntun to n bọ lọna. 
 
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa lorilẹ-ede Naijiria, Ọlanrewaju Nureni Adedoyin naa tẹnu mọ ọn pe awọn nilo iranlọwọ ijọba ipinlẹ Ogun lati pese awọn irinṣẹ lati gbogun ti iwa ọdaran ati iwa jagidijagan fun ifọkanbalẹ araalu ati ijọba funra rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI