VGN GBE OṢUBA KARE FUN GOMINA IPINLẸ KATSINA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 18, 2020

VGN GBE OṢUBA KARE FUN GOMINA IPINLẸ KATSINA


Adari ẹgbẹ fijilante lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Vigilante Group of Nigeria, Ọmọwe Usman Mohammed Jahun ti gbe oṣuba kare fun Gomina ipinlẹ Katsina, Ọnọrebu Aminu Bello Masari lori akitiyan rẹ lori bi wọn ṣe ri awọn akẹkọọ t'awọn Boko Haram ji gbe gba pada.
 
Awọn akẹkọọ naa ti ile-ẹkọ Government Science Secondary School to wa ni Kankara, ipinlẹ Katsina l'awọn Boko Haram ji gbe laipẹ yii, ti wọn si n dunkooko lati pa gbogbo wọn danu.
 
Adari ẹgbẹ VGN lapapọ, sọ pe awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ ti Gomina Masari gbe kalẹ lo ṣe iwadii ibi t'awọn akẹkọọ naa wa, ti wọn si ri wọn gba pada kuro lọwọ wọn.
 
Ninu atẹjade naa ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa lapapọ, Ọgbẹni Ọlanrewaju Nureni Adedoyin fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti pe awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ, paapaa lẹka eto aabo lati dide pese awọn nnkan idaabobo awọn ile ẹkọ, eyi to le dẹkun awọn oniṣẹ ibi lati ji awọn ọmọ gbe

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI