ṢỌUN T'ILU OGBOMỌṢỌ PADANU ỌMỌ RẸ, LẸYIN ỌDUN TO PADANU IJAPA ALAGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 3, 2020

ṢỌUN T'ILU OGBOMỌṢỌ PADANU ỌMỌ RẸ, LẸYIN ỌDUN TO PADANU IJAPA ALAGBA


Gbogbo ilu Ogbọmọṣọ n'ipinlẹ Ọyọ lo pa lọlọ lati ọjọ Aiku ti i ṣe Sande to kọja yii n'igba ti iroyin naa jade sita wi pe Ṣọun tilu Ogbomọṣọ, Ọba Jimọh Oyewunmi padanu ọkan lara awọn ọmọ rẹ, Olumide Oyewunmi.
 
Ojiṣẹ Ọlọrun ni wọn pe ọmọ Kabiyesi naa, ta a si gbọ pe ọjọ Sande lo dagbere f'aye.
 
AWIKONKO gbọ pe lẹyin ọdun kan ati oṣu meji ti ijapa to dagba julọ nilẹ adulawọ, iyẹn Alagba jade laye laafin Ṣọun naa ni ọmọ Kabiyesi naa f'aye silẹ.
 
Gbogbo awọn eeyan kaakiri orilẹ-ede Naijiria ati agbaye ni wọn ti n ba kabiyesi naa kẹdun iku ọmọ rẹ yii
 
Lara awọn to ba Kabiyesi kẹdun ni minisita fọrọ ere idaraya lorilẹ-ede yii, Ọgbẹni Sunday Dare, to si ni ibanujẹ lo jẹ f'oun nigba toun gbọ.
 
Ki Ọlọrun ba wa lọọra ẹmi kabiyesi at'awọn ọmọ rẹ yooku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI