Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba n'ipinlẹ Ondo, iyẹn Amọtẹkun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ lara awọn afurasi ti wọn ṣeku pa Ọba Israel Adeusi, Olufọn tilu Ifọn.
Ko si iwe iroyin naa ti ko gbe iroyin iku ọba yii, to si n jẹ kayeefi nla wipe wọn pa ọkan yinbọn pa ọkan lara awọn ọba ilẹ Yoruba.
Agbegbe kan ti wọn pe ni Elegbeka loju ọna Akurẹ-Benin-Ọrẹ n'ijọba ibilẹ Oṣe ni wọn pa kabiyesi naa danu si l'Ọjọbọ-Tọsidee ọsẹ to kọja.
Adari ẹgbẹ Amọtẹkun n'ipinlẹ naa, Oloye Adetunji Adelẹyẹ to fi ọrọ naa sita sọ pe iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wọn lo jẹ k'awọn ri awọn afurasi naa mu, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ wọn, ko si sọ iye awọn tọwọ tẹ naa.
Oloye Adelẹyẹ tun sọ pe awọn tun ti gba awọn mẹta kan ti wọn jigbe silẹ lọwọ awọn ajinigbe, to si l'awọn tun ṣi n ṣe iwadii wọn lọ.
No comments:
Post a Comment