OṢELU NI WỌN KI BỌ ỌRỌ ỌBA ONIRỌ, ẸJỌ WA NI KỌỌTU - ỌBA AROMAYẸ PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 14, 2020

OṢELU NI WỌN KI BỌ ỌRỌ ỌBA ONIRỌ, ẸJỌ WA NI KỌỌTU - ỌBA AROMAYẸ PARIWO SITA


Ọba Onirọ tilu Irọ, Ọba Nọjeemdeen Alani Aromayẹ ti sọ pe ko si nnkan meji to n lọ lori oun bi ko ṣe ọrọ oṣelu, eyi to ni wọn fi da owo oṣu at’awọn ẹtọ oun duro lawujọ awọnọba n’ipinlẹ Ogun.
 
 
Laipẹ yii ni iwe kan jade sita lori ikanni ayelujara, eyi ti alakoso lẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ n’ipinlẹ Ogun, Adesọji Adewuyi bu ọwọ lu wi pe ileeṣẹ naa ti da owo oṣu Ọba Nọjeedeen Alani Aromayẹ, Onirọ tilu Irọ duro d’igba ti ile ẹjọ kotẹmilọrun yoo pari ẹjọ naa. 
 
Ninu lẹta naa ti Ọgbẹni Adewuyi bu ọwọ lu lọjọ kẹrin oṣu yii ni wọn ti sọ pe awọn ti fi to igbimọ ọba nilu Ẹgba leti lati maa tọju awọn owo oṣu ọba Onirọ, k’awọn to o kọ lẹta mi in si wọn. Ati pe awọn tun ti gba ade lori ẹ, ko si ye e pe ara rẹ l’ọba alade, paapaa Ọba Onirọ. 
 
Nigba to n b’AWIKONKO sọrọ nilu Abẹokuta lonii, Ọba Aromayẹ ninu ọrọ rẹ sọ wi pe awọn ọmọ ilu Irọ ni wọn fi oun jẹ ọba naa lẹyin ti idilẹ Ẹlẹyọ fa oun kalẹ gẹgẹ bi ọba. 
 
Kabiyesi ni ko yẹ ki wọn ki ọrọ oṣelu bọ ipo ọba, paapaa n’igba to jẹ pe idile oun ni idile Ẹlẹyọ n’ipo naa tọ si, t’awọn mọlẹbi ko si tako oun. 
 
Eyi ni ọrọ ti Ọba Onirọ sọ: 
 
“Inu mi dun pupọ wi pe Ọmọba ni Gomina wa n’ipinlẹ Ogun, o si mọ awọn nnkan to tọ lori ọrọ ọlọba de. Lori ọba ti mo jẹ nilu Irọ, a ni iwe kan to jẹ gẹgẹ bi iwe ofin to si lagbara, iyẹn Gazzette, nibi ti awọn idile to lẹtọ si ipo ọba wa. Lati ọdun 1956 ni iwe yii ti a tun n pe ni Declaration ti wa. Idile mẹta lo n jẹ ọba nilu Irọ, akọkọ idile Ẹlẹyọ, idile keji ni Apetumata, idile kẹta ni Ẹribi. 
 
“Idile Ẹribi ti wọn ṣetan l’ọdun 2012. Igba t’awọn igbimọ ọlọba dide, ti wọn wo Gazzette ni wọn ri i pe idile Ẹlẹyọ lo kan, iyẹn idile ti mo ti jade wa. Ko to di pe awọn afọbajẹ kọ lẹta si wa lati mu ọmọ oye wa l’awọn idile Apetumata ti sare kọ lẹta s’awọn afọbajẹ wi pe idile Ẹlẹyọ ti l’awọn ko ni ọmọ oye. 
 
“Lẹsẹkẹsẹ l’awọn afọbajẹ ti da lẹta pada si wọn wi pe ko ti i kan idile wọn, idile Ẹlẹyọ lo kan. Ibẹ ni wọn wo o pe ki l’awọn le ṣe, to fi di pe wọn ri ẹnikan ṣoṣo gba mu ninu idile wa lati ba sọrọ, ẹni náà ní Adeleke Oniyide, ti awọn ìdílé Apẹtumata si ni ko da nnkan ru fun idile wa. Adeleke Oniyide ni wọn ń lo láti máa sọ kiri pe idile wa ko ni ọmọ òye, kí wọn gbé ipò náà lọ sí ìdílé Apẹtumata tí ipò kan lẹ́yìn tí wá. 
 
“Gbogbo awa mọlẹbi ti a le ni ọgọrun la sọ pe a ni ọmọ oye, ti a di dibo, ti wọn si dibo fun emi nikan lai si ija. Akọ̀wé ijọba ibilẹ lo wa ṣagbatẹru idibo naa fun wa, ẹri wa rẹpẹtẹ ti a le gbe kalẹ. Ọjọ mẹrinla ni wọn fi lẹ iwe sita wi pe awọn n bọ wa ṣeto idibo, ti ko si sẹni to tako o. Lẹyin eyi la ṣẹṣẹ bẹrẹ eto jijẹ ọba. Baba wa Alake naa fọwọ si i n’igba yẹn. Awọn afọbajẹ lọ sọdọ Alake, akọwe ijọba ibilẹ lọ sọdọ baba wa Alake, idile Ẹlẹyọ naa tun lọ lati f’idi ẹ mulẹ pe emi ni wọn fa kalẹ. 
 
“Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ ọdun 2014 ni wọn fun mi niwe gẹgẹ bi Onirọ tilu Irọ. Lẹyin naa ni idile Apetumata gbe ijọba ibilẹ lọ sile ẹjọ wi pe ko yẹ ijọba ibilẹ wa ṣeto idibo fun wa tori pe wọn ni a ti gba lati jẹ k’awọn j’ọba. Bi wọn ṣe de ile ẹjọ ni adajọ da ẹjọ wọn nu wi pe emi ni ọba. 
 
“Lẹyin ẹ ni wọn tun pada lọ si kọọtu, ti wọn si gba iwe injuction wa wi pe ki wọn ma jẹ ka se ayẹyẹ oye jijẹ, ti a si ti ṣe e ṣaaju. Ọdun kan lẹyin ẹ ni wọn tun gbe iwe kọọtu wa wi pe a tapa si ofin ile-ẹjọ. Awa naa si gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lati ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ. Lẹyin ẹ ni ijọba tun kọ lẹta pada fun mi wi pe ki n maa jẹ ọba mi lọ titi digba ti a maa fi pari ẹjọ nile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Ibadan. Ibi ti a ti bẹrẹ ree lati ọdun 2017 titi di ọdun 2020. 
 
“Ijọba mi in tun ti gbakoso n’ipinlẹ Ogun bayii, eyi to jẹ pe ọmọ ọba gan an ni Ọlọrun fi jẹ olori wa, ko si ni gbadura ki ade bọ lori ọba kankan. Laipẹ yii la n gbọ awuyewuye wi pe wọn fẹẹ da owo oṣu mi duro titi ta maa fi pari ẹjọ nilu Abẹokuta. Ọjọ kẹẹdogun oṣu keji ọdun 2021 ni igbẹjọ maa bẹrẹ nilu Ibadan. Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni ọdun 2021 la maa bẹrẹ igbẹjọ nilu Abẹokuta. 
 
“Ọgbọn ọjọ oṣu to kọja la lọ sile ẹjọ nilu Ibadan, ti wọn si sun ẹjọ́ siwaju di oṣu keji ọdun to n bọ ti i ṣe 2021, ti adajọ si gba gbogbo ẹjọ wa pátápátá wọlé wí pé ó bá òfin mu. 
 
“O wa ya mi lẹnu wi pe lọjọ kẹrin oṣu kejila ti a wa yii ni mo gba lẹta lati ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ n’ipinlẹ Ogun wi pe awọn ti kọ lẹta si igbimọ awọn ọba ilu Ẹgba wi pe ki wọn da owo oṣu mi duro, ki wọn si maa ba mi tọju ẹ, titi wọn tun maa fi kọ lẹka mi in. 
 
“Ṣaaju asiko yii la n jẹ k’ijọba ipinlẹ Ogun mọ pe ko sẹni to da ẹjọ nu nile ẹjọ kotẹmilọrun n'ilu Ibadan, iwe ipẹjọ si wa nilẹ. A tun sọ fún wọn pé aaye wa lati lọ sile ẹjọ náà, ki wọn lọ fidi ẹ mulẹ. Eyi to wa yani lẹnu ni ti ẹjọ injuction ti wọn da lọdun 2017 eyi ti a pe ẹjọ kotẹmilọrun le lori n’ijọba tun l’awọn fẹẹ gbe igbesẹ le lori, ti ko si ba oju mu, niwọn igba ti ẹjọ naa ṣi wa nile ẹjọ, ti wọn ko ti i dajọ. 
 
“Ko si ẹjọ kankan ti wọn danu lati ọdun 2017 titi de ọgbọn ọjọ oṣu kọkanla to kọja yii, ti wọn si tun ti sun si ọjọ kẹẹdogun oṣu keji ọdun to n bọ. Bẹẹ naa lo ri nile ẹjọ giga tilu Abẹokuta, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni la maa lọ sile ẹjọ náà l'Abẹokuta. Ṣe ẹ ti wa a ri pe wọn ti ki ọrọ oṣelu bọ ọrọ ọba Onirọ tilu Irọ. 
 
“Mo wa n fi asiko yii bẹ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun, ọmọ Naijiria lapapọ ki wọn ba wa bẹ ileeṣẹ tó ń rí sọ̀rọ̀ òfin n’ipinlẹ Ogun wi pe ki wọn ṣe nnkan to ba ofin mu. Ko sẹni to wa nidi gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ yii bi ko ṣe ọkunrin kan ti wọn n pe ni Niyi Ẹdun toun wa lati idile Apetumata tori pe oun gan an lo nifẹ si ipo ọba yii. Oun lo si n lo oṣelu tori oloṣelu ni. 
 
“Mo tun n fi asiko yii bẹ Gomina, Ọmọba Dapọ Abiọdun wi pe ki wọn ma jẹ ki ogun wọ ilu Irọ, tori pe idile Ẹlẹyọ ko ṣetan lati fi ipo yii silẹ fun idile kankan, tori pe ti ipo naa ba kan wọn, wọn ko ni i sọ pe ki idile Ẹlẹyọ maa bọ lati ṣe e.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI