ỌPẸ O! ỌBA TI WỌ́N JI GBÉ NI MỌṢALAṢI TI GBÀ ÒMÌNIRA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 21, 2020

ỌPẸ O! ỌBA TI WỌ́N JI GBÉ NI MỌṢALAṢI TI GBÀ ÒMÌNIRA


Ọjọ́ Ẹti, ìyẹn Fraide ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni wọn jì Ejeh tilu Akpa ni ìpínlẹ̀ Kogi, Alaaji Usman Sani gbé lásìkò tó fẹẹ wọ inú mọṣalaṣi láti kirun ni nnkan bí aago márùn-ún ààbọ̀ àárọ̀. 

A gbọ pé gbàrà tí wọn jì ọba náà gbé ní wón ti bẹ̀rẹ̀ si í pé àwọn mọlẹbi ẹ láti san owó tí kò dín ni mílíọ̀nù márùndinlọgbọn {N25m} láti fi gba ọba náà silẹ, ṣùgbọ́n tí wọn làwọn mọlẹbi ń bẹbẹ pé kí wọn gba mílíọ̀nù kan náírà lọ́wọ́ wọn. 

Lẹ́yìn idunadura là gbọ pé wọn fi ọba náà silẹ lọ́jọ́ Àìkú tí í ṣe Sannde àná. 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ìpínlẹ̀ Kogi, William Ovye Aya nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ sọ pé òun kò mọ nnkankan nípa wí pé wọn san owó gba ọba náà sílè. 

O ni nnkan tòun mọ ni pé lẹ́yìn tí ìròyìn náà tẹ wọn lọ́wọ́ wí pé wọn jì ọba náà gbé làwọn bẹ̀rẹ̀ ìwádìí, tí Ọlọ́run sì fún wọn ṣe láti rí ọba náà gbà kúrò lọ́wọ́ wọn.

Bẹ́ẹ̀ ni kò mẹnuba a wi pe ọwọ àwọn tẹ lára àwọn ajinigbe náà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI