OLÚBARÀ LÓ NI GBOGBO ÒKÈ-ÀTÀ, Ẹ KÌLỌ̀ FUN ỌMỌ ADẸTẸ TO N PE ARA RẸ NI BAALẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 9, 2020

OLÚBARÀ LÓ NI GBOGBO ÒKÈ-ÀTÀ, Ẹ KÌLỌ̀ FUN ỌMỌ ADẸTẸ TO N PE ARA RẸ NI BAALẸ


Ẹgbẹ awọn ọmọ ilu Ibara ti pariwo sita fun ọkunrin kan ti wọn lo n dunkooko lati dawọ ayẹyẹ ifinijoye to fẹẹ waye lopin ọsẹ yii nilu Ibara, iyẹn nibi ti Olubara tilu Ibara, Ọba {Dọkita} Jacob Olufẹmi Ọmọlade JP ti fẹẹ fi awọn baalẹ mẹfa jẹ duro, wi pe ko lọ so ewe agbejẹ m'ọwọ.
 
Laipẹ yii ni atẹjade kan tẹ AWIKONKO lọwọ, eyi t'awọn ọmọ ilu Ibara fi ọwọ si, nibi ti wọn ti n sọ pe Olubara lo ni gbogbo aṣẹ lati fi oloye tabi baalẹ jẹ, ati pe Olubara lo ni aṣẹ lori ilu Oke-Ata.
 
Atẹjade naa lọ bayii pe:
 
Latari pe gbogbo abule to wa ni Oke-Ata lo wa labẹ ilu Ibara pẹlu idara Kabiyesi Olubara tilu Ibara, Ọba Olufẹmi Jacob Ọmọlade, idi ree ti kabiyesi yoo tun ṣe fi awọn baalẹ mẹfa miran jẹ nilu Ọke-Ata l'ọjọ Satide to n bọ yii, iyẹn ọjọ kejila oṣu kejila ti a wa yii.
 
Awọn Baalẹ naa ni Oloye Olufẹmi Fagbẹmi ti abule Boṣero; Oloye Alao Oyelẹyẹ ti abulẹ Koto Aro; Oloye Sunday Akinlọtan ti abule Alapata; Ọmọba Rasheed Babatunde Adeyinka ti abule Igu-Ejo; Oloye Kayọde Akintunde ti abule Okoko ati Oloye Kamorudeen Agbogun ti abule Aro-Oropọ.
 
Gbogbo awọn abule yii pata lo wa labẹ ilu Ibara, idi ree ti Kabiyesi, Ọba (Dọkita) Olufẹmi Ọmọlade {JP}, ọba to jẹ ki Ṣodẹkẹ to de abẹ Olumọ yoo ṣe fi awọn baalẹ yii jẹ l'awọn abule naa.
 
Bẹ o ba si gbagbe, ọjọ kọkanlelogun oṣu kọkanla ọdun yii naa ni Kabiyesi Olubara fi Oloye AbdulGaniu Abiọdun Akinọla Akiọle {F'iwajoye Akọkọ} jẹ baale Oke-Ata Housing Estate, ti igba ọtun ati omi alaafia si tun n ru jade si i.
 
Kaabiyesi Ọba Lafa, Alaya Agbegba Do, igba yin a tubo maa tu wa lara o. Aṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI