Gbogbo agbaye patapata n'iroyin naa ṣi n ya lẹnu titi d'asiko ta a kọ iroyin yii tan, lori iku gbajugbaja onilu agbaye nni, Alaaji Ramọni Alao Adewọle ti ọpọ awọn eeyan mọ si Adewọle Oniluọla.
Alaaji Ramọni Adewọle lo jade laarọ oni ti i ṣe Ọjọru, iyẹn Wẹside lẹni ọdun mẹtadinlọgọrun (97).
Asiko ti wọn ṣẹṣẹ pari fiimu agbelewo ti wọn ṣe lati fi sọ itan igbesi aye Oloogbe Ayinla Ọmọwura, ẹni to ku l'ogoji ọdun sẹyin nilu Abẹokuta.
Oṣu to kọja yii ni Baba Adewọle Oniluọla ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdunmẹtadinlọgọrun rẹ nilu Abẹokuta.
Irọlẹ oni, laagọ mẹrin ni wọn yoo sinku baba naa nilana musulumi nilu Abẹokuta.
No comments:
Post a Comment