OGBOLOGBO ADIGUNJALE TUN PADE IKU OJIJI L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 7, 2020

OGBOLOGBO ADIGUNJALE TUN PADE IKU OJIJI L'OGUN


Itura nla lo tun de b'awọn to n rin lopopona Ṣagamu si Ikẹnnẹ bayii lori b'awọn ọlọpaa Mopol ṣe gbogun ti awọn adigunjale ti wọn n fojoojumọ d'awọn arin-rin-ajo lọna, ti wọn si pa ọkan lara wọn danu.
 
Alẹ ana la gbọ pe awọn adigunjale yii lọ d'awọn to n gba opopona yii lọna lati ja wọn lole, ti a si gbọ pe wọn ti gba mọto kan lọwọ ẹni to ni i.
 
Kete ti iroyin naa tẹ awọn ọlọpaa lọwọ la gbọ pe wọn ti sare lọ sibi ti wọn wa, ti wọn si doju kọ wọn.
 
Ibi ti wọn ti n jijakadi pẹlu ibọn la gbọ pe awọn ọlọpaa ti mu ẹyọkan balẹ ninu wọn, to si dagbere faye loju ẹsẹ. Wọn ni ṣe l'awọn yooku na papa bora, koda, ti wọn sọ pe pẹlu ọgbẹ ọta ibọn lawọn adigunjale naa fi salọ.
 
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti sọ pe oun ko le b'awọn ọdaran gbe inu ilu rara, paapaa julọ lasiko ti ọdun n wọle bọ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI