Muhtar Usman to jẹ ọga agba tẹlẹri n'ileeṣẹ ọkọ ofurufu orilẹ-ede yii, Nigerian Civil Aviation Authority (NCAA) n'iroyin tẹ wa lọwọ wi pe o ti jade laye lẹni ọdun mẹtalelọgọta (63).
Alẹ ana ti i ṣe Tusidee la gbọ pe Usman ku si ọsibitu kan nilu Zaria, ipinlẹ Kaduna.
Ọdun 2014 si ọdun 2019 to kọja la gbọ pe Usman fi jẹ ọga agba (Director-General) n'ileeṣẹ NCAA.
Kete to f'ipo naa silẹ ni Aarẹ Muhammadu Buhari yan Balogun Musa Nuhu lati rọpo ẹ.
No comments:
Post a Comment