Epe burúkú báwọn èèyàn ń gbé iyale ilé kan, Mary Omifuntọ ṣẹ títí di àsìkò tá a kọ ìròyìn yìí tán lórí bo ṣe dá omi gbígbóná lè ọmọ bibi inú ẹ, Kaosarat lórí.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ wá lọ́wọ́, wọn ní Mary sọ fún ọmọ rẹ, Kaosarat náà pé kò wá kiri oúnjẹ lọ, ìyẹn lọ́jọ́ Àìkú tí í ṣe Sannde tó kọjá yìí, tí wọn sì l'ọmọ náà lòun kò lè kiri.
Kí í ṣe àkọ́kọ́ rèé tí wọn ní ọmọ náà yóò máa bá màmá rẹ kiri oúnjẹ lágbègbè Oṣhodi n'ilu Èkó, ṣùgbọ́n tí wọn oúnjẹ ọjọ́ Sannde náà ni bo ṣe jẹ́.
A gbọ pé ẹran tí Mary tà kù lọ́jọ́ Satide - Abamẹta ló pọ̀, èyí tó fi pinnu láti dáná, kí àwọn ẹran náà má bá a bajẹ. Bó ṣe dáná náà tán lo pé Kaosarat tí wọn ní àkọ́bí rẹ ni pé kó wá gbé oúnjẹ náà kiri lọ.
Kaosarat ni wọn lo sọ pé òun kò lè kiri lọ, torí pé ara òun kò mokun dáadáa, èyí ni wón lo bí Mary nínú tó fi sọ igbaju fún Kaosarat, tí wọn sì nìyẹn sọ̀rọ̀ burúkú sí i.
Pẹlu ìbínú là gbọ pé Mary fi sáré lọ yọ igi ńlá kan láti là á mọ ọmọ rẹ yìí, ṣùgbọ́n tí wọn làwọn ara àdúgbò ni wọn sáré gba a lọ́wọ́ ẹ.
Ìbínú yìí ni wọn lo jẹ́ kó lọ gbé omi gbígbóná tó wà lórí iná tó ń dá lọ́wọ́, tó sì dá a sì ọmọ náà lára láti ẹyin.
Àwọn ẹlẹyinju àánú ládùúgbò náà là gbọ wọn sáré gbé ọmọ yìí lọ sí ọsibitu fún itọju, níbi tí wọn tí padà kọ àwọn òògùn tí wọn yóò ra fún un láti máa lo, kí ara rẹ lè dá. Wọn ní bí Mary ṣe rí ìwé tí wọn fi kọ ogun náà si lo tí fà á yà dànù.
Eyii gan lo bí àwọn èèyàn nínú tí wọn fi lọ fi tó àwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀ Oṣhodi-Isọlọ létí, táwọn yẹn sì lọ gbé e láti fọrọ wá a lẹnu wo.
Leyin eyi ni wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fà á lé àwọn ọlọpaa lọ́wọ́ láti gbé e lọ sílè ẹjọ́.
No comments:
Post a Comment