Gomina ipinlẹ Kano, Ganduje ti sọ pe oun ko kabamọ bi oun ṣe rọ Emir ilu Kano tẹlẹ, Sanusi Lamido Sanusi loye.
O
ni tẹlẹ gan an kii ṣe Sanusi lo tọ si ipo naa, awọn alagbara ijọba
nigba naa lo kan fi iyansipo rẹ ṣe ọna ati fi la aarẹ igba naa, Goodluck
Jonathan loju.
Gomina Ganduje to sọrọ nibi ifilọlẹ iwe kan nipa aarẹ ana, Goodluck Jonathan ṣalaye kikun nipa iṣẹlẹ naa.
O
ni wi pe lasiko ti wọn yan Sanusi Lamido Sanusi gẹgẹ bii Emi ilu Kano
loṣu kẹfa, ọdun 2020, lẹyin oṣu meji ti aarẹ Jonathan yọọ nipo gomina
banki apapọ Naijiria, oun mọ pe kii ṣe igbesẹ to tọ nigba naa.
O ni nikete ti oun di gomina loun ti sọ ọ fun ara oun pe oogun ti Jonathan lo lori ọrọ Sanusi ṣe pataki pupọ.
Ganduje ni aarẹ ana, Goodluck Jonathan gbe igbesẹ akin lati yọ Sanusi nipo gomina banki apapọ Naijiria nitootọ.
Bi
o tilẹ jẹ pe o fa ẹtanu rẹ laarin awọn eeyan kan; sibẹ oun ri i gẹgẹ bi
igbesẹ to tọ gẹgẹ bi oogun to yẹ ni lilo to dabi ọna abayọ lati wo
wahala igba naa.
"Oogun
naa, bi o tilẹ jẹ pe mi o kii ṣe dokita iṣegun oyinbo, oogun yii kan
naa yoo wulo fun iṣẹ kan naa, arun kan naa ati fun eeyan kan naa.
Ganduje ni: "Nitori naa mo gbe igbesẹ oogun ti Jonathan gbe lati doola ilana ati eto Ọba jijẹ ni Kano, mo si lo o daadaa.
Fun idi eyi. igun kan naa lemi ati aarẹ ana, Jonathan wa.
Ẹ wo o, emi ko kabamọ rara nitori pe mo yọ Sanusi loye Emir ti Kano"
Lasiko
iṣejọba Rabiu Kwankwaso gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Kano ni wọn fi Sanusi
Lamido Sanusi joye Ẹmir ilu Kano ṣugbọn ni ọjọ Kẹsan an oṣu kẹta ọdun
2020 ni wọn rọọ loye.
No comments:
Post a Comment