Ó MÀ ṢE O! GBAJÚMỌ̀ ÒṢERÉ TÍÁTÀ ONÍGBÀGBỌ́ PÀDÁNÙ ÌYÀWÓ Ẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 15, 2020

Ó MÀ ṢE O! GBAJÚMỌ̀ ÒṢERÉ TÍÁTÀ ONÍGBÀGBỌ́ PÀDÁNÙ ÌYÀWÓ Ẹ̀


Àsìkò yìí kì í ṣe asiko tó dára rárá fún gbajugbaja oṣere tíátà onigbagbọ nnì, Ajihinrere Doyin Hassan àti ìdílé rẹ lórí bo ṣe pàdánù ìyàwó ẹ, Ajihinrere Bọlanle Hassan. 

Ẹni ọdún mẹtadinlọgọta ni wọn pé Olóògbé Bọlanle kò tó jáde láyé lẹ́yìn àìsàn rampẹ. 

Ìlú oyinbo là gbọ pé àwọn èèyàn ń gbé látìgbà tí wọn tí fẹ ara wọn. Oríṣiríṣi fíìmù onigbagbọ làwọn méjèèjì tí kópa, tí wọn sì gbajumọ dáadáa. 

Ohun tó ń yà púpọ̀ àwọn èèyàn lénu ni bí wọn ṣe sọ pé fúnra obìnrin náà ló wa mọto lọ sí ọsibitu nígbà tó ṣàkíyèsí pé ara rẹ̀ kò fẹẹ yà, tó sì fẹẹ lọ ṣe àyẹ̀wò. 


Kò pẹ tó dé ọsibitu náà là gbọ pé ó dakẹ lásìkò tí wọn ń ṣe àyẹ̀wò fún un lọ́wọ́. Àìsàn tí wọn lo ń ṣe é náà ni wọn sọ pé ó ti wọ ọ lára gidi gan ko tó o fura.

Ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù yìí là gbọ pé wọn yóò ṣe ìsìn orin ìkẹyìn fún un ní ẹ̀ka ṣọọṣi Ridiimu tí Baba Adeboye tí wọn pé ní RCCG House of Favour to wa ni Redemption Camp laago mẹ́rin irọlẹ. 


Ibẹ náà sì ni wọn yóò ti ṣe ìsìn ìkẹyìn fún lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù yìí laago mẹ́wàá àárọ̀, kò tó di pé wọn fi eérú fún eérú, erupẹ fún erupẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI