NITORI OWO OṢU TUNTUN, AWỌN OṢIṢẸ FẸẸ FI IJA NLA PADE FAYẸMI L'EKITI L'ỌDUN 2021 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 30, 2020

NITORI OWO OṢU TUNTUN, AWỌN OṢIṢẸ FẸẸ FI IJA NLA PADE FAYẸMI L'EKITI L'ỌDUN 2021


Gbogbo igbaradi la gbọ pe ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ n'ipinlẹ Ekiti ti pari lati fi wahala nla koju Gomina ipinlẹ naa, Kayọde Fayẹmi lori owo oṣu tuntun t'ijọba apapọ paṣẹ rẹ fun gbogbo Gomina lati maa san, ṣugbọn ti wọn l'awọn ipinlẹ kọọkan ko ti i bẹrẹ.
 
Ẹgbẹ naa sọ pe bi Gomina Fayẹmi ko ba tete gbe igbesẹ lati bẹrẹ si i san owo oṣu tuntun ẹgbẹrun lọna ọgbọn naa, awọn yoo fi iwọde ifẹhonu han pade lọdun tuntun ti a fẹẹ bọ si yii ni, iyẹn bẹrẹ lati ọsẹ akọkọ ninu ọdun 2021 ti i ṣe ọsẹ to n bọ.
 
Yatọ si eyi, wọn l'awọn tun n fẹ ki Gomina Fayẹmi san gbogbo owo oṣu awọn to gba igbega, gẹgẹ bi ifẹnuko t'awọn jọ ṣe lai ya ẹka ileeṣẹ kankan silẹ. 
 
Bẹ o ba gbagbe, ni kete ti Aarẹ Buhari kede owo oṣu tuntun naa l'ọdun 2018 ni Gomina Fayẹmi ti sọ oun yoo bẹrẹ si i san owo naa f'awọn oṣiṣẹ lati ipele kinni ati ipele kẹfa, to si loun yoo jẹ ko yika laipẹ.
 
Ninu iapde ti wọn ṣe n'irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tuside ana, eyi ti wọn ṣeakojọpọ rẹ sinu iwe kan ti wọn gbe jade f'awọn oniroyin laaarọ oni ti i ṣe Wẹside ni wọn ti sọ pe awọn ti fẹnuko si opin nnkan t'awọn n fẹ, ko si si ayipada kankan, ayafi b'ijọba ba gbọ si wọn lẹnu.
 
Atẹjade naa ti alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti NLC, Kọmureedi Kọlapọ Ọlatunde ati ti TUC, Ṣọla Adigun to fi mọ JNC, Kayọde Faomiluyi bu ọwọ lu sọ pe ijọba ko ti i mu ileri rẹ ṣẹ lẹyin ipade t'awọn jọ ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI