Ọrọ buruku t'oun tẹrin laarọ oni ti i ṣe Ọjọbọ, iyẹn Tọsidee n'igba t'awọn akẹkọọ ile ẹkọ gbogboniṣe ti Moshood Abiọla Polytechnic to wa n'ilu Abẹokuta gbe akanṣe orin tuntun jade nitori idanwo wọn ti wọn fẹẹ ṣe l'ọsan onii.
Awọn akẹkọọ naa ti wọn wa ni ipele kẹta, iyẹn HND1 ni ẹka ikẹkọọ iṣẹ igbohunsafẹfẹ, iyẹn Mass Communication l'awọn akẹkọọ ti a n sọ yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni idanwo kan ti wọn pe ni Statistics, ti wọn tun n pe ni MAC 312 lo n ko ibẹrubojo si wọn lọkan.
AWIKONKO gbọ pe pupọ awọn akẹkọọ ni wọn ki i yege ninu idanwo naa lọdọọdun, to si jẹ pe awọn akẹkọọ ti ko din ni ọọdunrun (300) ti wọn kopa ninu idanwo yii l'ọdun to kọja ni wọn tun fẹ tun un ṣe lọdun yii.
Wọn ni aago kan ọsan ni idanwo naa fẹẹ waye ninu ọgba ile ẹkọ naa lonii.
Ori ikanni ayelujara ti ibaraẹnisọrọ, iyẹn Wasaapu (WhatsApp) to jẹ ti awọn akẹkọọ HND1 yii ni wọn gbe orin naa si, t'awọn eeyan si n gbadura kikan-kikan pe ki Ọlọrun ran awọn lọwọ.
Orin naa ti wọn fi ọhun orin ijọ ṣẹlẹ kọ, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ laago mẹwaa kọja iṣẹju mẹrindinlogun lọ bayii pe:
Oluwa wa, ọrọ wa d'ọwọ rẹ;
Oluwa wa, ọrọ wa d'ọwọ rẹ;
Ma ma jẹ ka pada wa l'ọdun to n bọ wa ṣe Stats
No comments:
Post a Comment