Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ti sọ pe b'awọn ọlọpaa ba mu ẹnikẹni lori ẹsun lilo mọto lọna ti ko yẹ, ki wọn ma ṣe pe oun nitori pe ofin ti wa lori ẹ.
Lai pẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa gbe atẹjade kan sita wi pe wọn yoo maa mu gbogbo awọn ti wọn ba n lo mọto ti ko ni nọmba idanimọ, at'awọn ti wọn n lẹ nnkan dudu mọ gilaasi mọto wọn, iyẹn tinted glass lai gba aṣẹ ọlọpaa, paapaa julọ awọn ti wọn ko ba duro fun ina to n dari ọkọ l'awọn yoo bẹrẹ si i mu, ti wọn yoo si maa f'oju wọn ba ile-ẹjọ.
Ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tusidee ana ni Oyeyẹmi gbe ọrọ naa sori ikanni ayelujara ti fesibuuku rẹ wi pe ki awọn ti ọwọ ba tẹ lori wi pe wọn tapa si ofin ma ṣe pe oun lati gba wọn silẹ, nitori pe oun ko ni i da si i.
Abimbọla Oyeyẹmi ni o ṣe pataki lati maa tẹle ofin orilẹ-ede yii.
No comments:
Post a Comment