Alaṣẹ, apaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church to wa nilu Eko, Primate Elijah
Ayọdele ti sọ pe ajakalẹ arun koronafairọọsi t'awọn eeyan tun n pe ni Covid-19 ti ṣetan lati tun gba ẹmi awọn gbajumọ oloṣelu lorilẹ-ede Naijiria.
Wolii Ayọdele lo sọrọ yii lonii ni nu atẹjade asọtẹlẹ to fi wi pe arun naa fẹẹ gbogun ti orilẹ-ede Naijiria, paapaa awọn to n mu ifasẹyin ba ilọsiwaju Naijiria.
Gbajumọ Wolii naa ni ajakalẹ arun yii ko ti i kasẹ nilẹ, tori pe ṣe lo n duro lati ran awọn ọta Naijiria lọ sọrun apapandodo.
Bakan naa lo tun sọ pe iku yoo ṣẹlẹ nile agbara orilẹ-ede yii ti a mọ si Aso Villa, eyi to wa nilu Abuja, to si n bẹ awọn ọmọ Naijiria lati gbadura lodi si iku awọn eeyan pataki lawujọ.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Covid-19 ṣetan lati pa pupọ awọn eeyan to n mu ifasẹyin ba orilẹ-ede Najiria, pupọ awọn gbajumọ ati eeyan nla-nla ni yoo ku danu nipasẹ Covid-19. Ẹ jẹ k'awọn ọmọ Naijiria darapọ mọ mi ninu adura lọjọ kinni ati ọjọ kẹrinla oṣu kinni ọdun 2021 lati gbadura lodi si iku nile agbara, arun Covid-29 ṣi wa nita.
"Ọlọrun n binu s'awọn to n dabaru nnkan lorilẹ-ede yii, yala ojiṣẹ Ọlọrun ni tabi oloṣelu tabi ẹnikẹni. Maa yannayanna ẹ pupọ lọjọ kejilelogun oṣu yii."
No comments:
Post a Comment