Ina esisi ko gbọdọ tun jo wa lẹẹkan si, ẹ ti papakọ ofurufu ki Covid-19 ma baa yọ wọle lẹẹkeeji.
Ikilọ ree lati ẹnu Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ ri Atiku Abubakar lori ọna ati dena itankalẹ arun Covid-19 lẹẹkeeji ni Naijiria.
Atiku to tun dije dupo aarẹ ninu idibo ọdun 2019 sọ pe aitete gbe igbesẹ ijọba nigba ti ajakalẹ akọkọ waye lo jẹ ki ọrọ di bo ti ṣe ri loni.
Loju opo rẹ ni Twitter lo kọ ọrọ yi si pẹlu bi ọwọja itankalẹ arun Covid-19 ṣe n peleke si ni Naijiria.
Atiku mu akawe bi awọn orileede miran nilẹ Yuroopu ti ṣe ti n ti bode wọn pẹlu ilẹ Gẹẹsi lọna ati kọdi itankalẹ ẹda Covid-19 kan to n ja rainrain ni ibẹ.
Ninu awọn orileede taa n sọ yi ni Italy, Belgium ati Netherlands wa.
O ni awọn orileede ti wọn ko jafara ti n gbe igbesẹ to yẹ nitori naa ki Naijiria di lilọ bibọ ọkọ ofurufu lati ilẹ Gẹẹsi si Naijiria ku.
Atiku pari ọrọ rẹ pe eto ilera Naijiria ko munadoko debi ti yoo le tọju awọn to ba lugbadi arun naa.
Igbọran gẹgẹ bi o ti ṣe wi, san ju ẹbọ ruru lọ.
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment