Gomina ipinlẹ Kwara AbdulRahman AbdulRazaq ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin Kristẹni yọ ayọ ọdun keresimesi to n lọ lọwọ yii, to si n gbadura pe ki Ọlọrun fi ṣe apẹẹrẹ rere fun gbogbo eeyan to n kopa ninu ẹ.
Ninu atẹjade ti Gomina AbdulRazaq fi sita lati ọwọ akọwe iroyin ẹ, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye lo ti jẹ ko di mimọ pe ọjọ ayọ nla ni o jẹ fun gbogbo eeyan, paapaa awọn ẹlẹsin kristẹni.
Gomina AbdulRazaq wa a gba awọn eeyan lamọran lati rọra ṣe ayẹyẹ ọdun keresimesi pẹlu ifẹ, iṣọkan ati alaafia, ati pe ki wọn gbadura fun alaafia orilẹ-ede Naijiria.
No comments:
Post a Comment