KERESIMESI: GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ, KASNATY FẸẸ PIN ẸBUN ỌDUN F'AWỌN ỌMỌDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 8, 2020

KERESIMESI: GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ, KASNATY FẸẸ PIN ẸBUN ỌDUN F'AWỌN ỌMỌDE


Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu idunnu nla ni pupọ awọn akẹkọọ ti wọn jẹ ọmọde kaakiri orilẹ-ede Naijiria wa lori bi ọkan lara awọn sọrọsọrọ ti okiki rẹ n kan gidi lasiko yii, Kọlawọle Adejojo, iyẹn Kasnaty Ṣugar ṣe fẹẹ pin ẹbun fun wọn. 
 
Kasnaty Ṣugar to jẹ alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Sugarlink Concepts ati Adejojo Communications la gbọ pe o fẹ fi awọn ẹbun ọdun naa mọ riri oore Ọlọrun nigbesi aye ẹ ni.

Bo tilẹ jẹ pe AWIKONKO ko ti i gbọ kulẹkulẹ nipa bi eto naa ṣe fẹ lọ si, ṣugbọn ta a gbọ pe ọkunrin naa ti tẹ iwe ajakọ (Exercise books) rẹpẹtẹ lati pin fun gbogbo awọn akẹkọọ patapata kaakiri orilẹ-ede Naijiria.


Yatọ si awọn iwe ajakọ yii, a tun gbọ pe oriṣiriṣi ẹbun lo ti wa nilẹ ti ọkunrin naa fẹẹ fun awọn ọmọde fun ti ọdun keresimesi to n bọ lọna yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI