‘Ẹ ṣaanu mi, iṣẹ eṣu ni’ lọrọ ẹbẹ to
n tenu gendekunrin kan ti wọn pe oruko e ni Idris Ayọtunde
jade lopin ọsẹ to kọja yii n’igba tọwọ ọlọpaa
tẹ ẹ
lori mọto onibara rẹ to jigbe nilu Eko, to si fẹ
lọ ta a danu silu Ibadan lowo pooku, ko to di pe aṣiri ẹ tu s’awọn ọlọpaa lọwọ.
Gẹgẹ ba a ṣe
gbo, wọn ni ọsẹ to kọja ni obinrin kan ti wọn pe ni
Shofidiya Tosin gbe mọto Ford ẹ ti nọmba
idanimọ ẹ
jẹ EPE 707 FM lọ sibi ti wọn ti n fọ mọto
lagbegbe Shasha Akowọnjọ nilu Eko, iyẹn nibi ti Idris ti n b’awọn
fọ mọto, to si fa kọkọrọ mọto
naa le Idris lọwọ lati ba a fọ ọ
tinu-tẹyin ati ẹnijiini mọto naa.
Wọn ni Idris sọ fun Toyin pe awọn ko
ni irinṣẹ ti wọn fi n fọ ẹnjiini mọto lọdọ awọn,
ati pe oun yoo gbe e lọ sibi t’oun ti le ri i fọ daadaa, eyi gan an ni wọn lo jẹ
ki obinrin naa gba lati fi kọkọrọ mọto
rẹ silẹ fun Idiris lọjọ
naa.
Oju ona la gbọ
pe Idris ti yi ero ọkan rẹ pada, to si gbe mọto naa salọ latigba naa. Awọn to f’iṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe ṣe ni Idris gbe mọto naa gba ilu Abẹokuta, to si fẹ lọ
ta a danu silu Ibadan, ko si ri owo gidi lati fi da iṣẹ
ara rẹ silẹ, iyẹn lojo Ẹti ti i ṣe
Fraidee to kọja yii.
A gbọ
pe ibi t’awọn ọlọpaa ti n yẹ awọn mọto to n kọja lọ
wo lagbegbe abule Alakija to wa n’ijọba ibilẹ
Ọdẹda ni wọn ti da Idris duro, ti wọn
si n beere awọn
iwe mọto naa lọwọ ẹ,
ṣugbọn ti ko ri i ko jade. Ọrọ ti wọn ni Idris n sọ lẹnu lo fu awọn ọlọpaa lara wi pe ki i ṣ’oun
lo ni mọto naa, ti wọn si gbe e lo teṣan wọn to wa nitosi.
Teṣan
naa ni wọn ni Idris ti pada jẹwọ pe ki wọn ṣe
oun jẹjẹ, tori pe ṣe
loun ji mọto naa gbe nibi toun ti n ṣiṣẹ
awọn to n fọ
mọto, ati pe oun fẹ lọ ta mọto naa danu ni, to si ni iṣẹ eṣu ni, ki wọn da aṣọ aṣiri b’oun.
Loju ẹsẹ l’awọn ọlọpaa ti kan s’awọn t’Ekoo, ti wọn si ni ẹni to ni mọto naa ti wa fi to awọn leti.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinle Ogun, Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn tarẹ Idris si ẹka
ileeṣẹ wọn
to n ṣe iwadii ọdaran lati le tẹsiwaju ninu ẹsun
ti wọn fi kan Idris, ko le tete f’oju ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment