IMỌTOTO: IJỌBA KWARA KEDE GBALEGBATA LỌJỌ SATIDE ỌLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 25, 2020

IMỌTOTO: IJỌBA KWARA KEDE GBALEGBATA LỌJỌ SATIDE ỌLA


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kede igbalegbata lọjọ keji ọdun keresimesi to jẹ Satide to gbẹyin ninu oṣu, iyẹn ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu yii.
 
Aarin agogo meje aarọ si mẹsan aarọ ni igbalegbata naa yoo waye kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa n'ipinlẹ naa. 
 
Ohun ta a gbọ ni pe ko ni si anfaani f'awọn eeyan lati rin kaakiri lasiko yii, bẹẹ si ni ko ni i si igbokegbodo ọkọ digba ti eto naa yoo wa s'opin.
 
Yatọ si eyi, awọn oṣiṣẹ ti yoo tọpinpin eto naa yoo lọ kaakiri, ti wọn yoo si f'iya jẹ awọn to ba tapa si ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI