Ile ẹjọ giga to wa ni Ikẹja n'ipinlẹ Eko ti sọ pe oun ko le faaye silẹ lati gba beeli gbajugba ojiṣẹ Ọlọrin nni, Wolii Ọladele Ogundipẹ t'ọpọ awọn eeyan mọ si Genesis.
Laipẹ yii ni ile ẹjọ sọ Wolii Genesis s'ẹwọn ọdun kan gbako pẹluu iṣẹ aṣekara lori ẹsun jibiti. Lẹyin idajọ naa ni agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Ọlanrewaju Ajanaku dide lati pe ẹjọ kotẹmilọrun, eyi to fi n bẹ ile ẹjọ lati tun idajọ naa yẹwo.
Ninu iwe alabala mẹrindinlogun ni wọn ti sọ pe Wolii Genesis ni aisan itọ ṣuga, ko si le fara mọ ọgba ẹwọn kirikiri naa, ati pe ipo to wa ti da oriṣiriṣi aisan si i lara, to si ni ki wọn faaye silẹ fun beeli lati tọju ara rẹ digba ti wọn yoo fi bẹrẹ ẹjọ kotẹmilọrun naa.
Onidajọ Ọlabisi Akinlade sọ pe ko saaye lati gba beeli naa.
No comments:
Post a Comment