Ko din ni ẹgbẹta akẹkọọ ti awọn agbebọn tun ti ji gbe salọ bayii n'ipinlẹ Katsina l'ọjọ Ẹti, Fraide ọsẹ to kọja yii.
Ile-ẹkọ Government Science
Secondary School to wa ni Kankara, ipinlẹ naa la gbọ pe awọn agbebọn yii yawọ ni nnkan bi aago mẹsan aabọ alẹ ọjọ naa, iyẹn ijẹta.
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni wọn ṣina ibọn bolẹ nigba ti wọn yawọ inu ọgba naa, eyi to ko ibẹrubojo s'ọkan awọn eeyan, ti wọn si n sa kijokijo lati sa asala fun ẹmi wọn.
Lẹyin eyi la gbọ pe wọn fo fẹnsi wọnu ọgba naa, ti wọn si bẹrẹ si i ṣe awọn ẹṣọ inu ọgba naa niṣekuṣe ko to di pe wọn ko awọn akẹkọọ naa sinu mọto wọn lọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Gambo Isa sọ pe loootọ ni ati pe awọn ti bẹrẹ iwadii.
No comments:
Post a Comment