GOMINA ABDULRAZAQ ṢE ABẸWO IBANIKẸDUN SI GOMINA ZULUM NI MAIDUGURI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 6, 2020

GOMINA ABDULRAZAQ ṢE ABẸWO IBANIKẸDUN SI GOMINA ZULUM NI MAIDUGURI


Lonii ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ṣe ibaẹwo ibanikẹdun si Gomina Babagana Umara Zulum t'ipinlẹ Borno lori b'awọn Boko Haram ṣe p'awọn agbẹ danu l'ọsẹ to kọja yii.
 
Abẹwo naa lo waye nile ijọba to wa ni Maiduguri ni Gomina AbdulRazaq ti kọwọ rin pẹlu awọn sẹnetọ Kwara bi i Sẹnetọ Ibrahim Yahya, Sẹnetọ Lọla Ashiru, Sẹnetọ Sadiq Umar ati oludamọran pataki fun Gomina nipa oṣelu, Sa'adu Salaudeen.

Laipẹ yii l'awọn Boko Haram ya wọ ilu Zabarmari, ti wọn si pa awọn agbẹ to le lọgọrun-un nipakupa.
 
Diẹ lara awọn to wa nibi abẹwo naa ree:








No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI