GOMINA ABDULRAZAQ, ỌNỌREBU SALIHU, SẸNETỌ OLORIẸGBẸ ṢABẸWO SI JẸBA LORI AWỌN ILE TO JONA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 25, 2020

GOMINA ABDULRAZAQ, ỌNỌREBU SALIHU, SẸNETỌ OLORIẸGBẸ ṢABẸWO SI JẸBA LORI AWỌN ILE TO JONA

Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq lo ti ṣe abẹwo ibanikẹdun si ilu Jẹba n'iọba ibilẹ Moro, ipinlẹ naa nibi ti awọn ile ti ko din ni mẹtalelogoji ti jona kọja sisọ.
 
Lara awọn to kọwọ rin pẹlu Gomina Abdulrazaq ni Ọnọrebu Yakubu Danladi Salihu to jẹ abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Sẹnetọ Yahya Oloriẹgbẹ to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Kwara nile igbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Sadiq Umar toun n ṣoju Kwara North, igbakeji olori ile igbimọ aṣofin, John Bello; awọn kọmiṣanna at'awọn ọgba lẹka eto ijọba.
 
 
Ọjọru ti i ṣe Wẹside to kọja yii la gbọ pe awọn eeyan padanu ẹni ẹmi wọn, ti oriṣiriṣi ile ati dukia si tun jọna kọja sisọ.
 
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti sọ pe awọn yoo wa ọna táwọn yoo fi ran awọn to padanu dukia wọn lọwọ pẹlu iwọnba ti agbara wọn ba ka.
 
"A  ni lati wa ọna abayọ sọrọ awọn eeyan ti wọn padanu dukia wọn, awọn kan padanu ẹmi wọn. Ki Ọlọrun ba wa tẹ wọn si afẹfẹ rere."
 
Bakan naa lo dupẹ lọwọ ijọba apapọ lori bi wọn ṣe n fẹ opopona Jẹba, to si ni iṣoro ti wọn n koju lori ọna yii ni ti aisi owo lati fi tẹsiwaju nitori ajakalẹ arun Covid-19.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI