Bi gbogbo awọn eeyan kaakiri agbaye, paapaa orilẹ-ede Naijiria ṣe n minisita fun ọrọ iroyin ati aṣa lorilẹ-ede yii, Lai Mohammed yọ fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkandinlaadọrin (69) lonii, ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara naa fi lẹta ayọ ranṣẹ ranṣẹ.
Ninu atẹjade ti Gomina AbdulRazaq fi ranṣẹ lo ti ṣapejuwe Lai Mohammed gẹgẹ bi aṣaaju to ni rere, ati oloṣenu agbẹnusọ to kun oju oṣuwọn lọna to ye kooro.
AbdulRazaq ni awọn ipa ti Lai Mohammed ti ko n'ipinlẹ Kwara, paapaap lorilẹ-ede Naijiria ko ṣee fọwọ rọ ti sẹyin, ati pe ipa rẹ ko le parẹ lailai.
O wa gbadura ẹmi gigun ati alaafia fun baba naa ninu ilera pipe.
No comments:
Post a Comment