GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ FẸẸ MI IGBORO ILU ABẸOKUTA TITI L'ỌJỌ KEJILELOGUN OṢU YII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 8, 2020

GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ FẸẸ MI IGBORO ILU ABẸOKUTA TITI L'ỌJỌ KEJILELOGUN OṢU YII


Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ayẹyẹ awọọdu ọlọdọọdun ti ọkan lara awọn agba sọrọsọrọ n'ipinlẹ Ogun, Oloye Makinde Fasunle maa n ṣagbatẹru ẹ, iyẹn Owuye Day Celebration and Award Presentation.
 
Ọjọ kejilelogun oṣu yii, iyẹn 22nd Decenber, 2020 ni eto awọọdu naa fẹẹ waye n'ilu Abẹokuta ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun. Gbọngan ayẹyẹ ti Ẹgba Inner Circle, to wa ni Abiọla Way, iyẹn ni adojukọ mọsalaṣi nla ti Alubarika ni ayẹyẹ naa yoo ti waye, bẹrẹ lati aago mejila ọsan.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Makinde Fasunle t'awọn ololufẹ ẹ tun mọ si Sẹnetọ ati Baba Owuyẹ lo fẹẹ fi awọọdu naa da awọn alatilẹyin ẹ, paapaa awọn to to ti ko ipa ribiribi lawujọ lọla.

Ki i ṣe akọkọ ree ti eto ayẹyẹ awọọdu yii yoo maa waye, ko da ti wọn ni awọn to fẹẹ gba awọọdu l'ọdun pọ kọja afẹnusọ.

Eto Owuyẹ, nibi ti ọkunrin naa ti n tu aṣiri awọn aṣebi-ṣeka kaakiri orilẹ-ede yii, iyẹn ni ileeṣẹ redio Fresh 107.9 to wa nilu Abẹokuta la gbọ pe ọkunrin naa fi sọri aami ẹyẹ yii.

Awọn gbajugbaja olorin nni, Ayọọla Akinọla Michael t'awọn eeyan n pe ni Alayọ Melody Singer ati Saint Janet ti yoo f'orin da awọn eeyan laraya lọjọ naa; ti Musiliu Sanni, iyẹn Bẹbẹ ati Abdul-Yọmi Matẹ, Ifankaleluya yoo si dari eto ọjọ naa.

Siwaju si i la tun gbọ pe wọn fẹẹ lo asiko naa lati fi ṣe ikowojọ miliọnu mẹwaa naira fun yara igbohunsilẹ ode oni (Digital Recording Studio) ti wọn fẹẹ ṣagbekalẹ ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI