FR MBAKA LU AWỌN AKỌROYIN BBC LALUBAMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, December 12, 2020

FR MBAKA LU AWỌN AKỌROYIN BBC LALUBAMI


Gbajugbaja ojisẹ Ọlọrun kan ninu ijọ Aguda katoliki, Fada Ejike Mbaka atawọn ọmọ ijọ rẹ kan kọlu awọn akọroyin BBC meji ati awakọ wọn nilu Enugu.
 
 
Awọn akọroyin naa, Chioma Obianinwa ati Nnamdi Agbanelo pẹlu awakọ wọn, Ndubuisi Nwafor ni awọn fada meji mii tẹle lọ sibi ifọrọwanilẹnuwo sọdọ Mbaka. 
 
Awọn fada mejeeji naa ni orukọ wọn n jẹ Cajethan Obiekezie ati igbakeji rẹ, Solomon Orakam.
 
Fada Obiekezie, to se agbatẹru eto ifọrọwanilẹnuwo naa, lo lewaju ikọ iroyin BBC lọ sinu ijọ Adoration Ministry ti Mbaka n lewaju rẹ ni deede aago mẹwa owurọ. 
 
Eto ifọrọwanilẹnuwo naa ko tete waye ni kete ti wọn de ile ijọsin naa, tori Mbaka n waasu lọwọ. 
 
Ikọ iroyin BBC ti Fada Obiekezie lewaju rẹ, wa morile ile Mbaka lẹyin ti isin naa pari ni deede aago marun irọlẹ lati seto ifọrọwanilẹnuwo ọhun. 
 
Nigba ti fada Mbaka si wọnu ile, awọn ikọ iroyin BBC wa ninu ọkọ wọn nita, ni Fada Obiekezie ba wọnu ile lati lọ jiroro pẹlu fada Mbaka, amọ ko pẹ ni awọn gende ọkunrin bii ogun yi mọto ikọ iroyin BBC ka. 
 
Gẹgẹ bi akọroyin wa, Chioma Obianinwa se salaye, awọn ọkunrin naa gba awọn irinsẹ akọroyin olowo iyebiye ti wọn gbe dani, ti wọn si dunkooko lati pa wọn danu nitori pe wọn ni wọn kọ 'awọn iroyin ti ko dara nipa Fada Mbaka'. 
 
Obianinwa ni "Mbaka sọ pe ka duro titi di ipari isin ti oun n se fun ifọrọwanilẹnuwo naa. Awọn ọkunrin to wa nita ile naa ni BBC Igbo maa n kọ iroyin ti ko dara nipa Mbaka. 
 
Wọn bẹrẹ si na Nnamdi, Solomon ati Ndubuisi. Won fun wọn ni ọpọ ọsẹ alagbara lori ati ni gbogbo ara." 
 
Akọroyin BBC naa tẹsiwaju pe Mbaka ati Obiekezie jade wa latinu ile nigba ti wọn gbọ ariwo ija to n lọ nita, ti Fada Mbaka si kọju si oun naa, bẹẹ lo n fi awọn ika ọwọ rẹ gun oun loju, to si n pe oun ni 'Elesu'. 
 
"Igbesẹ Mbaka yii gan lo sewuri fun awọn gende ọkunrin naa lati maa tẹsiwaju nidi ikọlu ti wọn n se, ti Fada Mbaka naa si n pariwo lati maa bu wa. 
 
O pasẹ fun awọn ọkunrin naa lati gba awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ ati ẹrọ ayaworan wa. 
 
Wọn ni awọn yoo pa wa lai si ohunkohun ti yoo sẹlẹ, ti wọn si si irun atọwọda ti mo de sori. 
 
Bakan naa ni wọn fun Nnamdi lọrun, ti Fada Obiekezie si n pariwo fun wọn lati dẹkun ikọlu naa sugbọn se ni wọn kọju ija si oun naa, ti wọn si gba ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ pẹlu." Chioma Salaye. 
 
Obianinwa ni ikọlu naa dawọ duro nigba ti oun pariwo pe "Gbogbo aye ni yoo mọ pe ile Fada Mbaka ni wọn ti pa awọn." 
 
"Igba yii ni Fada Mbaka wa sọ fun wa pe ka maa lọ ki awọn gende oun to pa wa. O pasẹ fun wọn pe ki wọn da awọn foonu ati irinsẹ wa ti wọn gba pada, ti wọn si le wa jade kuro ninu agbala wọn. 
 
Awọn ọkunrin naa tun n tẹle wa titi ta fi filu naa silẹ lọ gba iwosan ati iranwọ ọlọpaa." 
 
Nigba ti ileesẹ BBC pe Fada Mbaka lati oju opo Facebook rẹ, o ti pa aago rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI