EYI L'AṢIRI IKU TO PA KWANKWASO NI KANO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 25, 2020

EYI L'AṢIRI IKU TO PA KWANKWASO NI KANO


Baba Gomina ana n'ipinlẹ Kano, Rabi’u Musa Kwankwaso, iyẹn Alaaji Musa Sale Kwankwaso ti jade laye lẹni ọdun mẹtalelaadọrun (93).
 
Aarọ oni ni ti i ṣe Fraide ni Alaaji Musa Sale Kwankwaso jade laye.
 
Ọmọ rẹ, Sẹnetọ Kwankwaso lo kede iku baba wọn lori ikanni ayelujara ti Twitter, to si ni aago mẹta ọsan oni ni wọn yoo sinku baba naa ni Miller Road, Bompai, ipinlẹ Kano.
 
AWIKONKO gbọ pe ọmọ mọkandinlogun, eyi ti mẹwaa jẹ obinrin, ti mẹsan-an si jẹ ọkunrin l'awọn iyawo meji ti baba naa fẹ bi fun un, to si fi ọpọlọpọ ọmọ-ọmọ silẹ saye lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI