Kò dín ni ọba méje tí wọn gba ọ̀pá àti ìwé àṣẹ ni ìpínlẹ̀ Kwara lọ́jọ́ Ajé tí í ṣe Mọnde àná.
Ẹsẹ̀ kò sì gbà èrò ni gbàgede tí eto ayẹyẹ gbígba ọ̀pá àṣẹ àti ìwé ẹ̀rí náà, táwọn èèyàn sì kún fún ayọ̀ àti ìdùnnú ńlá.
Àwọn Ọba tuntun náà ni: Olokeopin tilu Oke-Opin, Ọba Ezekiel Ajibọla Arigbajoye; Onimasudo tí Masudo, Ọba Abdulwahab Bọlaji Usman; Aniwo tilu Afin, Ile-Ire, Ọba Simeon Ibiyinka Ọlaonipẹkun; Asa-Oro ti Alasaro, Ọba Moses Adeṣina.
Àwọn yòókù ni: Eleku tilu Odo-Eku, Ọba Abdulwahab Ogunbiyi; Oninaja ti Inaja Inaja-Alaro, Ọba Ganiyu Ọlarewaju; àti Onilupeju of Ilupeju, Ọba Muhammed Ọlanrewaju Ọdunade.
Nibe ni ìjọba ìpínlẹ̀ náà tí gba wọn nimọran wí pé kí wọn lo ipò wọn láti fi mú àlàáfíà, asọyepọ, iṣọkan àti ìfẹ́ bá ìlú tí wọn jẹ ọba lé lórí lai si ọ̀rọ ẹlẹyamẹya.
Nígbà tó ń gba ẹnu Gomina sọ̀rọ̀, Kọmiṣanna fún ìdàgbàsókè agbegbe àti ọrọ òye jíjẹ, Ọnọrebu Aliyu Saifudeen sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ rí ara wọn tán wí pé àwọn tí de ipele tó ga julọ láyé, kí wọn sì máa lo ipò náà láti fi fìyà jẹ àwọn èèyàn lọ́nà aitọ.
Ó sì jẹ kò ye wọn pé àlàáfíà lo ṣe pàtàkì láàárín ìlú.
No comments:
Post a Comment