Ẹ MÁA DÚPẸ́ FUN ÀÁNÚ DÍẸ̀-DÍẸ̀ TÍ Ẹ Ń RÍ GBÀ LÁSÌKÒ ÌJỌBA BUHARI - FẸMI ADEṢINA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 21, 2020

Ẹ MÁA DÚPẸ́ FUN ÀÁNÚ DÍẸ̀-DÍẸ̀ TÍ Ẹ Ń RÍ GBÀ LÁSÌKÒ ÌJỌBA BUHARI - FẸMI ADEṢINA


Agbẹnusọ Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina tí gba gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lamọran wí pé ṣe ló yẹ kí wọn máa dúpẹ́ fún àánú tí Ààrẹ Mohammadu Buhari fi ń hàn fún wọn ní gbogbo ìgbà dípò kí wọn máa wà àṣìṣe. 

Fẹmi Adeṣina lo sọ̀rọ̀ yìí lọ́jọ́ Àìkú tí í ṣe Sannde àná níbi ifọrọwerọ tó ṣe pẹ̀lú ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels. 

O ni awon àsìkò kan wà, pàápàá nínú ìjọba àná tó jẹ́ pé ojoojumọ ni àwọn Boko Haram ń ju bọmbu láti pá àwọn aráàlú dànù, tó sì ni kò sí irú ẹ mọ lásìkò yìí. 

Adeṣina lo ń dáhùn ìbéèrè kan tí wọn bí í pé àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ lórí bí àìsí eto ààbò ṣe ń fojoojumọ pọ sì i. 

O ni nígbà ìṣàkóso ìjọba àná, ó máa ń to ẹẹmẹfa lojumọ tí àwọn Boko Haram máa ń ju bọmbu láti pá àwọn èèyàn dànù. 

Àti pé látìgbà tí Ààrẹ Buhari tó gbà ìjọba irú ìwà yìí kò ṣẹlẹ̀ mọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI