Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajugbaja ọja kan to wa ni Ipata, ijọba ibilẹ Ilọrin East jona, nibi ti ṣọọbu ti ko din ni mọkanla ti jona di eeru.
Ijọba ipinlẹ naa ti wa a ba awọn to padanu dukia ati ọja wọn kẹdun, to si l'awọn yooo gbe igbesẹ iranlọwọ f'awọn ọlọja naa.
Nígba to n gba ẹnu ijọba sọrọ, kọmiṣanna fun ọrọ oye jijẹ ati idagbasoke agbegbe, Arc Aliyu Muhammad
Saifuddeen sọ pe adanu nla ni ina naa jẹ fun awọn ọlọja, paapaa ijọba ipinlẹ naa.
O ni asiko t'awọn eeyan ṣẹṣẹ n bọ kuro ninu wahala eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ lorilẹ-ede yii ni ina naa deedee ṣẹyọ, to si tun ko awọn eeyan sinu oko gbese.
Saifuddeen wa a sọ pe awọn ti bẹrẹ itọpinpin lati mọ awọn nnkan to bajẹ, ki ijọba le ran wọn lọwọ.
No comments:
Post a Comment