Ọkan lara awọn gbajumọ Sẹnetọ lorilẹ-ede Naijira, Sẹnetọ Dino Melaye to ṣoju ẹkun Kogi ti n rawọ ẹbẹ si Aarẹ ana lorilẹ-ede yii, Goodluck Ebele Jonathan wi pe ko dariji oun, tori pe oju oun ti la s'awọn aṣiṣe nla toun hu si Aarẹ ana.
Melaye sọ pe awọn iwa t'oun hu si goodluck Jonathan ko ṣeyin bi oju oun ṣe dudu, toun ko si mọ nnkan toun n ṣe, ati pe ni bayii, iye oun ti sọ pada, oun si ti i ri i pe aṣiṣe nla gba a loun hu.
Lasiko ti wọn n se ifilọlẹ iwe kan ti wọn fi peri Jonathan ni Melaye fi ọrọ yi lede nilu Abuja.
Lara
awọn to doju ija kọ ijọba Jonathan ni idibo ọdun 2015 ni Melaye wa to
si polongo takuntakun lati tako Aarẹ ana naa ati awọn igbesẹ ti ijọba rẹ
gbe paapa julọ nipa aabo ati eto ọrọ aje.
Dino ṣalaye pe lọpọ igba ni igbe aye oun ko dan mọran laarin ọdun marun to kọja yii debi pe oun fẹẹ le gbẹmi ara oun.
''Emi
Sẹnẹtọ Dino Melaye mo sọ nitagbangba pe lẹyin ọpọ isẹlẹ ati awọn ohun
toju wa ti ri bayi, mo fẹ sọ pe nigba kan loju mi di, ṣugbọn bayi o ti
la kedere."
Bẹẹ naa ni Melaye gbosuba kare fun Aarẹ Jonathan fun igbesẹ pipe aarẹ Buhari lori ago lati gba pe oun padanu ibo ọdun 2015.
O
ni labẹ eleyi ati iwoye iru nkan to n sẹlẹ ni Amẹrika ti aarẹ Donald
Trump ko fẹ gba pe oun ti fidirẹmi ninu idibo, o yẹ ka kan saara si
Jonathan.
Yatọ
si Dino Melaye, awọn eekan miran to wa nibi ifilọlẹ iwe yi ti wọn pe
akọle rẹ ni "Dear President Goodluck Jonathan (An Open Letter)," ti
akọroyin kan Bonaventure Philips Melah kọ, tunbọ gbosuba kare fun
Jonathan.
Lara
wọn ni Gomina ipinlẹ Kano to wa ninu ẹgbẹ oselu APC to ni awọn mọ riri
eto Almajiri ti aarẹ Jonathan gbe kalẹ lati koju ipenija awọn ọmọ
Almajiri ti ko ri ẹkọ to peye gba.
Aarẹ
Jonathan ni aarẹ Nigeria akọkọ to pe alatako lati ki i ku orire aseyọri
ninu idibo botilẹ jẹ wipe awọn kan sọ pe ijọba rẹ faye gba awọn
aisedeede kan bi iwa ajẹbanu ati aidoju ija kọ awọn ikọ Boko Haram bo ti
se yẹ.
No comments:
Post a Comment