DIẸ LARA AWỌN ASỌTẸLẸ PRIMATE AYỌDELE TO TI WA S'IMUṢẸ L'ỌDUN 2020 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 13, 2020

DIẸ LARA AWỌN ASỌTẸLẸ PRIMATE AYỌDELE TO TI WA S'IMUṢẸ L'ỌDUN 2020


O ti di aṣa ọdọọdun f'awọn ojiṣẹ Ọlọrun, paap awọn wolii lati maa sọ awọn nnkan ti yoo ṣẹlẹ l'ọdun tuntun ti a ba bọ si. B'awọn Woli eke ṣe wa naa l'awọn ti Ọlọrun fi iṣẹ naa pọ rẹpẹtẹ, lara awọn ti Ọlọrun si fi iṣẹ asọtẹlẹ ran si ile aye Wolii Elijah Ayọdele wa.
 
Gbajugba ojiṣẹ Ọlọrun ni Wolii Primate Elijah Ayọdele to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical spiritual church lorilẹ-ede Naijiria.
 
L'ọdun to kọja ni Wolii Ayọdele sọ nipa awọn nnkan ti yoo ṣẹlẹ l'ọdun 2020 to n pari lọ yii, ti lara awọn asọtẹlẹ naa si ti wa si imuṣẹ pẹlu ogo Ọlọrun.
 
Diẹ ree lara awọn asọtẹlẹ to ti wa si imuṣẹ ree:
 
*Ajakalẹ Arun Koronafairọọsi: Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kejila ọdun to kọja ni Wolii Ayọdele pe ipade awọn oniroyin, nibi to ti sọ nipa awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ l'ọdun yii. nibẹ lo ti sọ pe ajalu nla kan n bọ lagbaye, eyi ti yoo sọ rudurudu si awọn orilẹ-ede kaakiri agbaye. Ko pẹ ni a bẹrẹ si i gbọ lọtun losi pe ajalẹ arun kan ti dide, aisan iba nla si ni, eyi ti wọn pe ni Covid-19, iyẹn Koronafairọọsi. Titi di asiko ta a pari akojọpọ yii l'awọn orilẹ-ede kan ko ti i bọ ninu ẹ.
 
*Ipadanu Donal Trump l'Amẹrika: Nibi ipade awọn oniroyin yii kan naa ni Wolii Ayódele tun ti mẹnuba pa Aarẹ ilẹ Amẹrika, iyẹn Donal Trump wi pe yoo padanu ibo ẹlẹẹkeji rẹ, ati pe yoo tun koju awọn wahala kọọkan ki asiko idibo naa to o de. Si iyalẹnu, ni ibẹrẹ ọdun yii l'awọn igbimọ dide lati yọ Trump danu, ṣugbọn ti wọn pada kuna. Bo tilẹ jẹ pe Trump funra rẹ ko ti i gba wi pe oun padanu, ṣugbọn sibẹ, Joe Biden lo jawe olubori.
 
*BREXIT: Wolii Ayọdele tun sọ pe oun ri i wi pe ilẹ Amẹrika ya kuro labẹ ajọ agbaye ti European Union. L'oṣu kinni ọdun yii ni asọtẹlẹ naa waye.
 
*Igbimọ buruku lodi si Aarẹ ilẹ Mali: Wolii Ayọdele ninu asọtẹlẹ rẹ sọ pe igbimọ buruku kan yoo dide lodi si Aarẹ orilẹ-ede Mali, ati pe k'awọn ọmọ orilẹ-ede naa dide gbadura lodi si ifẹhonu han. Gbogbo eeyan lo ri b'awọn ologun ṣe gba ijọba kuro lọwọ Aarẹ naa laipẹ yii.
 
*Ipaniyan kaakiri Naijiria: Nibẹ ni Wolii Ayọdele ti gba awọn ọmọ orilẹ-ede yii lamọran wi pe ki wọn kun fun adura lodi si ipaniyan-nipakupa. Ọpọ ni ko kọbi ara si i, ṣugbọn lonii, awọn t'awọn oniṣẹ buburu ti pa ko ṣee fẹnu sọ tan.
 
*Oku mẹfa ni Aso Villa: Bakan naa ni Wolii Ayọdele tun sọ pe k'awọn eeyan gbadura lodi si iku nile agbara orilẹ-ede yii, iyẹn Aso Villa. Oṣi diẹ lẹyin eyi ni olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ, Abba Kyari jade laye, ọkan lara awọn oṣiṣẹ iyawo Aarẹ Buhari naa jade laye.
 
*Awọn ọta Tinubu yoo dide: Ẹni ti ko mọ nnkankan nipa oṣelu gan an mọ pe awọn ọta alagbara dide si Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, to si jẹ pe ko ti i bọ ninu ẹ dasiko yii. Lara awọn asọtẹlẹ Wolii Ayọdele ni.
 
*Iku awọn gomina ana: Gomina n'ipinlẹ Kaduna, Balarabe Musa jade laye l'ọdun yii; Gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi jade laye.
 
*Awọn ọtọkulu ti yoo ba ajakalẹ arun Covid-19 lọ: A fi bi a ba fẹẹ tan ara wa jẹ, awọn gbajumọ oloṣelu at'awọn eeyan pataki lawujọ ni wọn ba ajakalẹ arun Covid-19 lọ, lara wọn si ni Oloye Abiọla Ajimọbi, Abba Kyari, Sẹnetọ Bayọ Ọṣinọwọ; Sẹnetọ Buruji Kaṣhamu at'awọn mi in ni arun naa pa danu. Bi Wolii Ayọdele ṣe sọ pe ajakalẹ arun kan n bọ lo ti sọ pe awọn alagbara ni arun naa fẹẹ mu lọ lorilẹ-ede yii, to si ni k'awọn eeyan gbadura fun wọn.

*Aṣeyọri Ọbasẹki l'Edo: N'igba t'awọn eeyan ko tiẹ ro pe Ọbasẹki tun le pada sipo naa lẹẹkeji, Wolii Ayọdele sọ pe ko si bi ogun 'se le dide to si Gomina ipinlẹ Ẹdo, iyén Godwin Ọbasẹki, sibẹ yoo jawe olubori.
 
*Yiyọ Ọṣhiọmhọlẹ danu n'ipo alaga APC: Wolii Ayọdele kilọ gidi fun Adams Ọṣhiọmhọlẹ lati ma ṣe ba Ọbasẹki ja, tori pe yoo pada gba idojuti nla. Kete ti ẹgbẹ oṣelu APC gba Ọbasẹki wọle lati jade du ipo Gomina ni ile ẹjọ da Ọṣhiọmhọlẹ duro gẹgẹ bi alaga, ti wọn ko si jẹ ko pari saa rẹ.

*Akeredolu l'Ondo: Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ṣi asọtẹlẹ yii gbọ, ṣugbọn sibẹ ọrọ naa wa si imuṣẹ pe Gomina Oluwarotimi Akeredolu yoo jawe olubori lẹẹkeji l'Ondo.

*Yiyọ awọn abẹnugọn ile igbimọ aṣofin nipo: Bi wọn ṣe yọ abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Imo naa ni wọn yọ ti ipinlẹ Ẹdo bi ẹni jiga, ti t'ipinlẹ Gombe naa ko si gbẹyin.

*Kikọlu ọkọ Gomina: Wolii Ọlọrun yii tun sọ pe oun ri awọn Gomina kan ti wọn kọlu ọkọ akọwọrin wọn, ati pe ki wọn gbadura lodi si ikọlu tabi ijamba to le mu ẹmi wọn lọ. Ni nnkan bi oṣu meloo kan sẹyin ni wọn kọlu gomina ipinlẹ Borno, ti gomina si dori bọlẹ, t'awọn ọlọpaa rẹ si ku; wọn kọlu Gomina ipinlẹ Kwara, igbakeji gomina ipinlẹ Ogun ati Gomina Gboyega Oyetọla.
 
*Atunto ninu iṣẹ ọlọpaa: Ninu iwe ọlọdọọdun Wolii Ayọdele to ṣe l'ọdun yii loṣu kẹjọ lo ti sọ pe awọn atunto kan yoo waye ninu iṣẹ ọlọpaa. Ko pẹ ni wọn tu awọn ọlọpaa SARS ka kaakiri Naijiria.
 
*Yiyọ ọba alade nipo ati ina laafin: Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe wọn ti yọ Emir ilu Kano, Sanusi Lamido Sanusi n'ipo, bẹẹ si ni ki i ṣe iroyin mọ pe apa kan ninu aafin Ọọni Ifẹ jona. Ṣaaju asiko yii ni Wolii Ayọdele ti sọ asọtẹlẹ yii wi pe ki wọn gbadura f'awọn ọba kan lorilẹ-ee yii.
 
Diẹ ree lara awọn aṣotẹlẹ naa to ti wa si imuṣẹ lọdun, t'awọn mi in naa si tun wa si imuṣẹ ta o le mu wa fun un yin, lara wọn si ni jijawe olubori Aarẹ ilẹ Ghana, Akufo-Addo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI