ÀWỌN ÀGBẸ̀ ÌRẸSÌ BỌ́ SÁYÉ NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 21, 2020

ÀWỌN ÀGBẸ̀ ÌRẸSÌ BỌ́ SÁYÉ NI KWARA


Ṣẹkẹn báyìí ni inu awọn àgbẹ̀ tí wọn ń dá oko ìrẹsì ni ìpínlẹ̀ Kwara ń dùn lórí bí ìjọba ṣe ṣagbatẹru owó iranwọ fún wọn láti fi dá oko ìrẹsì lọ́dún yìí sí ọdún tó ń bọ̀. 

Banki àpapọ̀ orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn Central Bank of Nigeria là gbọ́ pé ó fẹẹ gbé owó tó lè ní ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù náírà kalẹ, ìyẹn N115m fún àwọn àgbẹ̀ náà. 

Ilẹ̀ tí kò dín ni 420 hectares là gbọ́ pé ó ti wà nílẹ̀ báyìí láti fi dá oko ìrẹsì náà láàárín ọdún yìí sí ọdún 2021.

Ko si nnkan méjì tí wọn lo jẹ́ kí ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara fọwọ́ sọya lórí àwọn àgbẹ̀ náà bí kò ṣe pé ẹnu wọn kò, wọn si n se nnkan gẹ́gẹ́ bo ti tọ́ àti bó ti yẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI