AWỌN ADIGUNJALE TUN YAWỌ IBADAN, WỌN PA ỌLỌDẸ DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 13, 2020

AWỌN ADIGUNJALE TUN YAWỌ IBADAN, WỌN PA ỌLỌDẸ DANU


Gbogbo agbegbe Mọniya to wa nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lọjọ Satide ana lo pa lọlọ n'igba ti wọn l'awọn adigunjalẹ yawọ ile epo kan nibẹ, ti wọn si pa ọlọdẹ danu.
 
Isau Yisah ni wọn pe orukọ ọlọdẹ naa ti wọn pa nipakupa loru Satide ana si ile epo ti wọn pe ni Tybato to wa lagbegbe Asanmajana ni Mọniya.
 
A gbọ pe ṣe ni awọn ọlọdẹ inu ọgba ile epo yii kọju ija s'awọn adigunjale naa nigba ti wọn debẹ, ṣugbọn ti wọn ni agbara wọn ko ka awọn ọlọdẹ yii, eyi to mu ki wọn pa ọkan danu lara wọn.
 
Bo tilẹ jẹ pe oriṣirṣi l'awọn eeyan n sọ nipa iku ọlọdẹ, nitori ti wọn sọ pe tori o da ninu awọn adigunjale naa mọ lo jẹ ki wọn pa a ki aṣiri ma ba a tu.
 
A gbọ pe ṣe ni wọn fọ igi mọ Isau, ẹni ọdun mẹtalelogoji naa lori to fi ku, ti wọn si gbe tẹlifiṣan at'awọn nnkan mi in salọ.
 
Ọgbẹni Olugbenga Fadeyi to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa f'idi iṣẹlẹ yii mulẹ, to si l'awọn ti bẹrẹ iwadii wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI