AṢIRU, FẸMI ATI IDRIS YOO GBADURA OPIN ỌDUN LỌGBA ẸWỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, December 31, 2020

AṢIRU, FẸMI ATI IDRIS YOO GBADURA OPIN ỌDUN LỌGBA ẸWỌN


Ọwọ ileeṣẹ eleto aabo So-Safe Corps n'ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun Aake, iyẹn Black Axe mẹta kan nilu Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun.
 
 
Agbegbe Satina lọwọ ti tẹ awọn mẹtẹẹta ti wọn pe orukọ wọn ni Aṣiru Aṣa, Fẹmi ati Idris. 
 
Ọsẹ to kọja lọ lọhun la gbọ pe awọn ara adugbo yii ta ileeṣẹ So-Safe lolobo wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n fojoojumọ ko ọkan awọn eeyan soke, pẹlu bi wọn ṣe ni wọn n fi agbara han ara wọn.
 
Loju ẹsẹ ni wọn ni ọga wọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe k'awọn ọmọ ogun wọn bẹrẹ iwadii, ti aṣiri si tu si wọn lọwọ. Wọn ni asiko ti wọn bẹrẹ wahala gangan lọwọ palaba wọn segi.
 
Alukoro ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Mọruf Yusuf sọ pe loju ẹsẹ tọwọ ti tẹ wọn laarọ ana ti i ṣe Wẹsidee l'awọn ko wọn lọ f'awọn ọlọpaa Igbẹba fun iwadii lẹkunrẹrẹ.
 
Bẹẹ l'awọn tun gba ibọn ati oriṣiriṣi nnkan oloro lọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI