Gbogbo awọn ara ati olugbe ipinlẹ Eko ni wọn ti dide adura gbigbona bayii fun Gomina wọn, Babajide Sanwo-Olu lori ajakalẹ arun korona to kọluu lojiji.
Kọmiṣanna fun eto ilera n'ipinlẹ Eko, Dọkita Akin Abayọmi lo kede sita lalẹ ana ti i ṣe Satide-Abamẹta pe Gomina Sanwo-Olu ti ko arun naa.
O ni ọjọ Fraide ijẹta ni Gomina Sanwo-Olu ko arun naa lẹyin ayẹwo ti wọn ṣe fun un, eyi to f'idi rẹ mulẹ, ati pe o ti wa n'ibi to ti n gba itọju ni IDH to wa ni Yaba.
Dọkita Abayọmi ni ko ni pẹ Gomina yoo fi bọ lọwọ arun naa pẹlu awọn itọju ti wọn n fun un nibẹ.
AWIKONKO gbọ pe bi iroyin naa ṣe jade sita l'awọn ọmọ Eko ti bẹrẹ aawẹ ati adura gbigbona fun GominaSanwo-Olu.
No comments:
Post a Comment