AISHA, ÌYÀWÓ BUHARI ṢÀLÀYÉ ÌDÍ TO FI KÚRÒ NÍLÙÚ LỌ DUBAI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 21, 2020

AISHA, ÌYÀWÓ BUHARI ṢÀLÀYÉ ÌDÍ TO FI KÚRÒ NÍLÙÚ LỌ DUBAI


Ìyàwó Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí, Aisha Buhari tí sọ pé òun kò sá kúrò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà nítorí àìsí eto ààbò tó péye, àti pé àwọn tó ń gbé awuyewuye náà káàkiri kò mọ nnkan ti wọn n sọ ní. 

Aisha lo sọ̀rọ̀ náà láti ẹnu ọkàn lára àwọn agbẹnusọ rẹ, Kabiru Dodo n'ilu Jalingo, ìpínlẹ̀ Taraba níbi tó ti fún àwọn opó lẹ́bùn nípasẹ̀ àjọ aláàánú tó dá sílẹ̀. 

Dodo sọ pé kí í ṣe pé Aisha déédéé fi ọkọ rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti mọlẹbi rẹ silẹ kúrò n'ilu, ó sọ pé ó ní bo ṣé jẹ́. 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ, o sọ pe "Ìyàwó Ààrẹ rìn irin àjò nítorí ìlera ara rẹ ní, àyẹ̀wò ara rẹ ló lọ ṣe, kí í ṣe pé ó kúrò n'ilu nítorí àìsí eto ààbò. 

"Ohun táwọn èèyàn ń sọ kò lẹsẹ nílẹ́ rárá, kò sì lè jẹ́ nnkan ti wọn lé kà kún rárá. 

"Mo fẹ́ sọ fún gbogbo àgbáyé wí pé mo máa ń gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀ lọpọlọpọ ìgbà, ó sì ṣetan láti padà silu nígbà tó bá parí àyẹ̀wò ìlera tó lọ ṣe lókè òkun."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI