ABDULFATAH, GOMINA ANA N'IPINLẸ KWARA ṢALAYE OHUN TO BA LỌ S'ỌDỌ EFCC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, December 8, 2020

ABDULFATAH, GOMINA ANA N'IPINLẸ KWARA ṢALAYE OHUN TO BA LỌ S'ỌDỌ EFCC


Gomina ana n'ipinlẹ Kwara, AbdulFatah Ahmed ti ṣalaye idi to fi lọ sọdọ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede yii, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, to si l'oun lọ jẹ ipe ti wọn pe oun ni.
 
Ahmed funra rẹ la gbọ pe o ṣalaye ọrọ naa ninu atẹjade to gbe sita lonii, ọjọ Iṣẹgun-Tusidee wi pe oun ti lọ s'ọdọ ajọ EFCC ti wọn ranṣẹ pe oun, to si ni ọjọ Aje ti i ṣe Mọnde ana loun lọ si ileeṣẹ to wa n'ilu Ilọrin, ipinlẹ naa.
 
Saa meji ni Alaaji AbdulFatah Ahmed ṣe gẹgẹ bi i gomina ipinlẹ Kwara, iyẹn laaarin ọdun 2011 si ọdun 2019 to kọja.
 
Oriṣiriṣi ẹsun iwa ajẹbanu ni wọn fi kan an ni kete to gbe ijọba silẹ fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq to wa nibẹ lọwọlọwọ.
 
Ninu atẹjade naa, Ahmed sọ pe:
 
"Lanaa, mo lọ si ẹkun ileeṣẹ EFCC to wa nilu Ilọrin, lẹyin ti wọn fi iwe pe mi. Nibẹ, mo ṣalaye awọn eto iṣuna wa ati awọn iduna-dura ti a ṣe lasiko ti mo jẹ Gomina. Ko si ẹsun ṣiṣẹ owo kumọkumọ ti wọn fi kan mi. Mo si ti pada sile mi."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI