Bi ipade t'awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ṣe pẹlu Gomina ana n'ipinlẹ Ekiti, Peter Ayọdele fayoṣe ba fi yọri si rere, a jẹ pe alaafia ti n de bọ diẹdiẹ ninu ẹgbẹ naa niyẹn, ṣugbọn bi ko ba ri bẹẹ, a jẹ adura ẹgbẹ oṣelu All Progressiveṣ Congress lo ṣi n gba niyẹn.
Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe wahala ẹni ti yoo jẹ olori ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba n waye laaarin Fayoṣe ati Gomina Ṣeyi Makinde t'ipinlẹ Ọyọ, ti ẹgbẹ naa si ti ṣe bẹẹ pin si meji ọtọọtọ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Gomina ana nípinlẹ Ọṣun, Ọlagunsoye Oyinlọla lo lewaju awọn agba ẹgbẹ PDP nilẹ Yoruba lọ sile Gomina Fayoṣe lati ṣe ipade alaafia lati yanju gbogbo aawọ ati wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni igbakeji alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ lapapọ, Ọmọwe Eddy Ọlafẹsọ; ọkan lara awọn apaṣẹ ẹgbẹ naa tẹlẹ, Ọmọwe Saka Balogun; Fẹmi Babalọla, Alaaji Adebisi Olopoeniyan; Rev Bunmi Jẹnyọ.
Awọn mi in l'awọn oloye ẹgbẹ naa n'ipinlẹ Ogun, Ekiti ati Eko bi i Ọmọwe Sikirulai Ogundele, Ọtunba Bisi Kọlawọle, Adedeji Doherty ati Sunday Bisi.
AWIKONKO gbọ pe bi itẹsiwaju ati iṣọkan yoo ṣe pada sinu ẹgbẹ naa fun igbaradi ibo ọdun 2023 ni wọn lọ ṣe pẹlu Fayoṣe ati lati yanju aawọ to wa laaarin oun pẹlu Gomina Makinde.
Bi ẹ ba ranti Ọlagunsoye Oyinlọla ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti wọn jẹ ti Gomina Makinde yan gẹgẹ bi alaga igbimọ ti yoo ri si bi wọn yoo ṣe yanju aawọ ninu ẹgbẹ naa, eyi si ni wọn lo mu ko gbe igbesẹ lati wa ọna abayọ lati ba Fayoṣe sọrọ.
No comments:
Post a Comment