WỌN JU ỌMỌ NAIJIRIA S'ẸWỌN L'AMẸRIKA, ALIBABA LO LU NI JIBITI OWO NLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, November 1, 2020

WỌN JU ỌMỌ NAIJIRIA S'ẸWỌN L'AMẸRIKA, ALIBABA LO LU NI JIBITI OWO NLA


Ẹwọn ọdun mẹrin aabọ gbako ni Nosa Onaghise yoo lo lọgba ẹwọn ilẹ Amẹrika lori bo ṣe lu gbajumọ ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Business Email Compromise t'ọpọ awọn eeyan mọ si Alibaba ni jibiti obitibiti owo.
 
Ọjọbọ-Tọside to kọja yii ni ile ẹjọ ilẹ Amẹrika kan, iyẹn US District Court to wa ni Austin texas lo sọ Nosa, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn naa ni jibiti owo to din diẹ ni miliọnu meji dọla ($1.7m).
 
Ile ẹjọ naa tun paṣẹ pe ki Nosa da $1.6m pada ninu owo naa ti wa ba ninu apo ifowopamọ si ẹ.
 
 
Lẹyin ti Nosa ba tun pari ẹwọn rẹ tan, yoo tun wa labẹ iṣakoso ile Amẹrika fun ọdun mẹta gbako, ti ko si ni le da ohunkohun ṣe funra rẹ lai gba aṣẹ.
 
Aarin ọdun 2016 si 2019 la gbọ pe Nosa fi ja ileeṣẹ yii lole milọnu mẹwaa dọla gbako.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI