WỌN FỌ ÒṢÌṢẸ́ LASTMA LORI NI LEKKI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 9, 2020

WỌN FỌ ÒṢÌṢẸ́ LASTMA LORI NI LEKKI


Kò dájú pé ọkùnrin kan tí wọn loo fọ òṣìṣẹ́ ojú popona tí ipinlẹ Èkó, ìyẹn LASTMA lórí yóò bọ nínú wàhálà afọwọfa náà. 

Wọn ní ṣe ni òṣìṣẹ́ LASTMA náà ń gbìyànjú láti sọ fún ọkùnrin ọ̀hún pé kò lọ gba afárá, dípò kó gba ojú pópónà tí mọto ń gbà kọjá pẹ̀lú ère asapajude. 

Agbegbe kan tí wọn pé ni Jakande to wá ní Lẹkki, ipinlẹ Èkó ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé. 

Ohun tí a gbọ ni pé ibi tí òṣìṣẹ́ LASTMA náà tí ń darí àwọn mọto tó ń kọjá lọkunrin náà tí lọ bá a wí pé kò bá òun dá mọto dúró láti kọjá. 

Wọn ní ṣe ni òṣìṣẹ́ LASTMA náà sọ pé kò lọ gba orí afara, àti pé ona náà kì í ṣe ibi tó lè gbà. 

Lójú ẹsẹ̀ ni wọn ní ọkùnrin náà pé àwọn èèyàn jọ, tí wọn sì dáwọ jọ lu òṣìṣẹ́ náà lórí fọ́. 

pẹ̀lú iranlọwọ àwọn ṣọja ni wọn fi rí ọkùnrin náà mú, tí wọn sì mú un lọ teṣan ọlọpaa 








No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI