WỌN FI OṢELU NLA HAN GBAJUMỌ ỌNỌREBU L'ONDO, LO BA L'AWỌN ṢẸṢẸ BẸRẸ IJA NI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, November 24, 2020

WỌN FI OṢELU NLA HAN GBAJUMỌ ỌNỌREBU L'ONDO, LO BA L'AWỌN ṢẸṢẸ BẸRẸ IJA NI


L'asiko ta a kọ iroyin yii tan, ara ko r'okun, bẹẹ ni ara ko ro adiẹ ni wọn fi n fi ọrọ naa ṣe nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, lori b'awọn ọnọrebu ti wọn dibo yan ṣe kọju ija sira wọn, ti wọn si n yọ ara wọn n'ipo.
 
Oni ti i ṣe Tusidee ni awọn ọmọ ilẹ igbimọ aṣofin ti ko din ni ogun dibo lati yọ ọkan lara wọn to jẹ igbakeji abẹnugọn ile igbimọ naa, Ọnọrebu Ogundeji Iroju n'ipo, ti wọn si yan ẹlomin in loju ẹsẹ lati rọpo ẹ.
 
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni Ọnọrebu Iroju wa lara awọn Ọnọrebu mẹsan-an ti wọn kọ lati bu ọwọ lu iwe irọloye igbakeji ana fun Gomina ipinlẹ naa, iyẹn Ọgbẹni Kayọde Ajayi lasiko to lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mi in.
 
Ọnọrebu Tọmide Akinrogunde la gbọ pe o daba naa pe ki wọn yọ Ọnọrebu Iroju pẹlu awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu ṣiṣe owo kumọkumọ ti wọn fi kan an, ti wọn si kede Ọnọrebu Aderọboye Samuel t'oun n ṣoju agbegbe Odigbo
 
Nibẹ naa ni wọn tun ti yan awọn mi in gẹgẹ bi i Ọnọrebu Oluwọle Ogunmọlasuyi lati di ọlori awọn ile igbimọ to pọ ju; Ọnọrebu Akingbaṣọ Festus lati di olori awọn ọmọ igbimọ to kere julọ ati Ọnọrebu Taofeek Mohammed gẹgẹ bi i Chief Whip.
 
Loju ẹsẹ la tun gbọ pe wọn ti gbe igbimọ dide lati tọpinpin awọn ẹsun ti wọn fi kan Ọnọrebu Iroju, ki wọn si tete jabọ abajade wọn.
 
N'igba to n sọrọ lori bi wọn ṣe yọ ọ nipo, Ọnọrebu Iroju sọ pe eremọde lasan ni wọn n ṣe, ati pe ohun ti wọn ṣe naa ko le fẹsẹ mulẹ lailai nitori pe ọna ti ko ba ofin mu ni wọn gba, to si l'awọn ṣẹṣẹ bẹrẹ wahala naa ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI