Gomina Yahaya Bello t'ipinlẹ Kogi ti sọ pe oun yo fi imu awọn to gbe atéjade sita lati fi kun owo ori burẹdi, eyi to loun ko mọ nnkakan nipa rẹ papa, to si ni iwa aburu patapata gba a ni.
Bẹ o ba gbagbe, ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin ni atẹjade kan jade sita wi pe ijọba ipinlẹ Kogi labẹ Gomina Yahaya Bello ti bu ọwọ lu ẹkunwo owo ori burẹdi ti wọn n ṣe jade n'ipinlẹ naa, ti wọn si ni ileeṣẹ to n ri si b'owo ṣe n wọle n'ipinlẹ naa ni wọn gbe igbesẹ yii.
Gomina Bello ni oun yoo f'imu awọn to gbe ipinnu naa sita lai jẹ k'oun mọ nipa rẹ danrin, ati pe oun yoo f'iya to tọ jẹ wọn gẹgẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Ilu Abuja ni Gomina Bello ti sọrọ yii lasiko to n b'awọn aṣojukọroyin sọrọ lẹyin ipade to ṣe pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lana ti i ṣe Tusidee.
O l'awọn ti n ṣe iwadii awọn to wa n'idi iwa buruku naa, tori pe iwa ọdaju pọmbele ni, ati pe oun ti sọ fun olori awọn oṣiṣẹ ijọba lati bẹrẹ iwadii naa.
No comments:
Post a Comment