Pupọ awọn ololufẹ gbajugbaja olorin takasufee nni, David Adedeji Adeleke t'ọpọ awọn eeyan mọ si Davido ni wọn n binu si i lori awọn ọrọ to kọ sori ikanni ayelujara laipẹ yii.
Davido lo kọ ọ sori ikanni ayelujara ti Twitter rẹ, nibi to si sọ awọn nnkan t'oun fẹ ki wọn maa fi ranti oun yatọ si orin toun n kọ.
Davido to ṣẹṣẹ gbe orin kan to pe ni 'A Better Time' jade sọrọ lanaa ti i ṣe Sanndee-Aiku wi pe oun fẹ k'awọn eeyan maa ranti oun nipa awọn nnkan rere t'oun ti ṣe, ati aanu toun n ṣe f'awọn eeyan, ati pe oun tun fẹ k'awọn eeyan maa ranti oun pe orukọ rere loun n fun Naijiria ati Afrika kaakiri agbaye.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ọpọ nnkan ni mo fẹ k'awọn eeyan maa fi ranti mi, ki i ṣe nipa orin ti mo n kọ nikan. Mo fẹ ki wọn maa ranti pe mo n sin awọn eeyan, ati pe ọpọ awọn eeyan ni wọn n jeere lara ibukun mi.
"Mo fun ẹbi mi lorukọ rere, mo fun orilẹ-ede mi lorukọ rere, mo fun gbogbo ilẹ Afrika lorukọ rere"
Bi Davido ṣe sọrọ yii l'awọn eeyan ti bẹrẹ si i sọ oriṣiriṣi, t'awọn kan si n beere pe ṣe ki i ṣe aroko ati owe ni Davido n fi awọn ọrọ rẹ yii ṣe f'awọn ololufẹ rẹ.
Wọn ni ko ma jẹ pe nnkankan fẹẹ ṣẹlẹ si i laipẹ, to fi ronu lati kọ iru nnkan to kọ sita yii, nitori pe o ṣi kere lati maa sọ iru awọn ọrọ wọnyii jade lẹnu, ati pe awọn ko ti i fẹ padanu ẹ lasiko yii.
Pupọ awọn ololufẹ ẹ ni wọn n binu si ọrọ to kọ yii.
No comments:
Post a Comment