Kani ki i ṣe ọpọlọpẹ Ọlọrun ati adura to wa lori ọkan lara awọn ọmọ gbajugbaja akewi nni, Azeez Ajobiewe ni, o ṣee ṣe ko jẹ pe nnkan ta n kọ yii kọ lai o ba maa kọ, ṣugbọn nipa ifẹ adẹdaa lori fi ko o yọ lọwọ iku ojiji.
Ọjọ Aiku-Sannde ijẹta la gbọ pe Ajibiewe at'awọn ikọ akọwọrin ẹ ti wọn jọ n fi ewi dawọn eeyan laraya kiri jọ n bọ lati ode ariya kan ko to di pe tanka elepo kan dee de lọ kọlu wọn.
Tanka elepo naa ni wọn lo o n sare asapajude lọ, to si dee de lọ kọlu Ajobiewe at'awọn eeyan ninu mọto ti ọn wa, to si jẹ pe ṣe ni mọto naa run jege.
Funra Azeez lo kọrin idupẹ naa sori ikanni ayelujara wi pe k'awọn eeyan maa ba oun ki ẹlẹda baba oun to n tẹle oun kaakiri ni gbogbo igba.
No comments:
Post a Comment