ỌPẸ́ O! OWÓ ARÚGBÓ TÚN FẸẸ GBA Ọ̀NÀ ÀRÀ YỌ L'ỌSẸ YÌÍ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 30, 2020

ỌPẸ́ O! OWÓ ARÚGBÓ TÚN FẸẸ GBA Ọ̀NÀ ÀRÀ YỌ L'ỌSẸ YÌÍ


Lásìkò tá a kọ ìròyìn yìí tán, inú ìdùnnú àti ayọ̀ ńlá ni gbogbo àwọn arúgbó káàkiri ìpínlẹ̀ Kwara wá lórí owó iranwọ tí ìjọba ìpínlẹ̀ ń fún wọn. 

Orin ọpẹ tí gbogbo àwọn arúgbó ìpínlẹ̀ náà ń kọ báyìí ni pé 'ọsẹ yìí l' ọsẹ ayọ̀ mi, mo ti fi ìgbàgbọ́ gba ire mi ò, ibanujẹ ayé tí dẹyin lẹ́yìn mi...'

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kí í ṣe àkọ́kọ́ rèé táwọn arúgbó yóò máa gba owó yìí, nítorí tá a gbọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá làwọn arúgbó tí wọn jẹ àǹfààní owó yìí nínú ipele àkọ́kọ́. 

Òní tí í ṣe ọjọ́ Ajé, Mọnde ni ipele min ín yóò tún bẹ̀rẹ̀ fáwọn tí wọn kò ti í jẹ irú àǹfààní báyìí, tí a sì gbọ pé báwọn kan yóò ṣe máa tẹwọ gba owó náà lọ́wọ́ àwọn aṣojú ìjọba, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò tún máa fi ranṣẹ sínú àpò ilé ifowopamọ, ìyẹn Banki àwọn mi ín. 

Àwọn àgbàlagbà tí ọjọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti ọgọ́ta ọdún lọ sókè là gbọ pé wọn láǹfààní sì owó yìí, tí a sì gbọ pé arúgbó tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náà ni wọn yóò tún jẹ́ àǹfààní tí kò wọ́pọ̀ yìí. 



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI