Bí ìjọba àpapọ̀ orílè èdè yìí bá fi etí sí àwọn ẹ̀bẹ̀ ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun, a jẹ pe oriire ńlá tún ti padà dé bá ipinlẹ Ogun nìyẹn, àti pé ògo ìlú Ẹ̀gbá tó ti sọnù tipẹ tún ti padà wọlé wá.
Ana tí i ṣe ọjọ́ Iṣẹgun-Tusidee ni Gómìnà Abiọdun kọ orin sì ìjọba àpapọ̀ létí wí pé kí wọ́n sọ aṣọ àṣà ipinlẹ náà, ìyẹn aṣọ Àdìrẹ́ di ohun tí wọn ń lo fáwọn ètò ńláńlá tàbí ayẹyẹ onírúurú lorilẹ-ede Nàìjíríà.
Níbi eto ọlọdọọdun nnì tí wọn fi ń gbé aṣọ àṣà ipinlẹ Ogun, Àdìrẹ́ lárugẹ, èyí tí wọn pé ni ÀDÌRẸ́ ÒGÙN ni ìpè yìí tí wáyé láti ẹnu Gómìnà Abiọdun.
Gbọngan àṣà ipinlẹ Ogun, ìyẹn June 12 Cultural Centre to wá ní Kutọ n'ilu Abẹ́òkúta ni eto naa ti waye, níbi ti Alakẹ ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ tí gbawọn èèyàn lálejò.
Nibẹ tún ti Gómìnà Abiọdun tí sọ pé aṣọ náà yóò jẹ ọkàn lára àwọn aṣọ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò máa wọ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún tó ń bọ̀, ìyẹn 2021.
Alaaji Lai Mohammed to je Minisita f'ọrọ àṣà, iroyin àti irin àjò afẹ́ lorilẹ-ede Nàìjíríà nígbà tó ń sọ̀rọ̀ sọ pé aṣọ Àdìrẹ́ náà wá lára àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì tí ìjọba àpapọ̀ ń fojú sọ́nà fún láti tún máa fi pá owó wọlé fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
No comments:
Post a Comment